Aṣiri Nla Ni Adekunle Gold Tu Yii O, A Ṣe Diẹ Lo Ku, Adekunle Gold ati Simi Iba Ti Ma Fẹ’rawọn

Aṣiri Nla Ni Adekunle Gold Tu Yii O, A Ṣe Diẹ Lo Ku, Adekunle Gold ati Simi Iba Ti Ma Fẹ'rawọn

Awọn gbajumọ tọkọtaya to tun jẹ onkọrin ilẹ wa, Adekunle Kosọkọ iyẹn Adekunle Gold ati aya rẹ, Simisọla Ogunlẹyẹ Kosọkọ t’awọn aye mọ si Simi ni aṣiri ti ọpọ awọn eeyan o gbọ ri ni’pa igbeyawo wọn tu si’ta laipẹ yii.

Dekunle Gold, ojulowo ọmọ Eko lati idile Kosọkọ to jọ ọkọ ninu igbeyawo naa gan-an lo fi ẹnu ara rẹ tu aṣiri naa, botilẹjẹ pe igbeyawo awọn mejeeji yii lo ti la ọpọlọpọ iji lile kọja, ti oniruuru aṣiri si ti tu si’ta. Koda awọn ahesọ naa pẹlu. Amọ aṣiri eyi ni Adekunle Gold t’awọn kan n pe ni AG Baby fun’ra rẹ wa si’ta wa gbe s’eti araye.

Ori eto (podcast) kan ti wọn n pe ni “One54 Podcast” ti AG Baby ti kopa laipẹ yii lo ti ṣ’alaye pe oun iba gbe ọrọ ifẹ oun ati Simi ju danu si’gbo bo ba ṣe pe ọrọ pada pakasọ ni. O ni ifẹ kankan to wa l’aarin awọn mejeeji o ni le wọ.

Alaye Adekunle ni pe oun gẹgẹ bii ẹda ta bi pẹlu abuda ailera SS ti awọn ṣọja inu ara wọn o dape to, l’eyi to ma n fa wọn si’nu ailera ati inira l’ọpọ igba. Adekunle ni bo ba ṣe pe abuda Simi jẹ ẹya AS abi SS ni, o ni oun o ni ro pe ẹẹmeji t’oun yoo fi tari ifẹ wọn s’odo, ko ma b’omi lọ nitori ko mu ọpọlọ dani rara ki awọn ololufẹ meji o t’ori ifẹ wọn ma pe awọn ọmọ wa’ye wa ma jẹ irora ailera gbogbo igba. O ni eyi ko da rara.

O ṣ’alaye tẹsiwaju pe, igba ti ọrọ ifẹ oun ati ololufẹ rẹ, Simi to pada di aya rẹ, pẹlu ọmọ meji l’aarin wọn ti fẹ ma d’ohun, l’oun ti kọkọ tete wadi iru abuda Simi, t’oun si ri pe abuda AA to ba abuda SS t’oun lọ, bi bẹẹ kọ oun o ti ẹ ni duro ki ọrọ ifẹ awọn wọ’ra.

Yatọ fun pe Adekunle Gold jẹ gbajumọ olorin, o tun jẹ ẹni to ti la ipenija ailera oorekoore kọja latari jijẹ ẹda to ni abuda SS, l’eyi to pada sọ di alagbawi nla fun idanilẹkọọ takọ idapọ to le bi ọmọ ti abuda rẹ yoo jẹ SS, to si ti n ṣiṣẹ agbawi naa karakara lati igba wa.

Simi ati Adekunle Gold ni wọn gbe’ra wọn ni’yawo gẹgẹ bii l’ọkọ-l’aya ni ọdun 2019, ti igbeyawo naa si ti so eso meji, akọ ati abo, ti akọbi jẹ abo, ti orukọ rẹ n jẹ Deja ti wọn yọ jade lati inu orukọ “Adejare” to jẹ ẹkunrẹrẹ orukọ rẹ.

Deja lo ti n gbajumọ bọ lati inu oyun t’awọn obi rẹ ti n kọrin fun, eyi to gbajumọ julọ ninu awọn orin naa ni “Dudukẹ”. Lẹyin ti ọmọ naa d’aye tan, lo ba tun ya aṣamu ọmọ to ṣ’enu ṣamu-ṣamu, tọpọ awọn eeyan si ti da mọ l’ori ayelujara, koda o ti ṣi’de ode orin kan fun baba rẹ ri ni ilu London ni’bi ọdun 2025 to kọja.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search