Obinrin To Ba L’owo Ju Ọkunrin Lọ O Le Pẹ Ni’le Ọkọ – Gehgeh

Obinrin To Ba L'owo Ju Ọkunrin Lọ O Le Pẹ Ni'le Ọkọ - Gehgeh

Agbefọnranjade to tun maa n tọ awọn eeyan s’ọna lori bi a ṣe n na owo, Emmanuel Oboruste ti gbogbo eeyan mọ si Gehgeh ti ṣalaye ero rẹ lori ki eeyan fẹ ẹni to ni owo ati ipo ju lọ ati igbagbọ rẹ pe awọn ọkunrin mii maa n mọọmọ wa obinrin to ni ju wọn lọ ni.

Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwanilẹnuwo kan, o fi awọn ọkunrin ti wọn wa lati ẹya Urhobo ṣ’apẹrẹ pe fifẹ ẹni to ga ju eeyan lọ l’awujo ati idokowo ye wọn gidi.

O ni bi obinrin ba ti ri pe oun riṣe ju ọkunrin lọ kii fẹ tẹriba. Gehgeh ni nkan ti ọkunrin Urhobo maa n ṣe ti wọn ba pade obinrin to ni ju wọn lọ ni pe wọn maa fi ṣe akaba ọla de ibi giga ṣugbọn ti obinrin naa o ba gba, o maa ja julẹ nitori igba diẹ naa ni naa a fi fẹ ko to ja ju silẹ.

O fi kun pe l’ọjọ ti obìnrin ba ti ri ṣe, awọn to ni ju lọ lo maa maa wo, ko ni wa awọn ọkunrin ti o ni to, bẹẹ lo ṣalaye pe idi re ti awọn ọkunrin Urhobo ṣe maa n fi wọn wa ọrọ fun ara wọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, iyatọ wa to ba jẹ ọkunrin Urhobo lo ni owo lọwọ o maa re obinrin to ba n fẹ de bi pe ko ni ni dagbasoke ju lọ, nitori oun ti ọkunrin na ni gbogbo eeyan lo ni ṣugbọn bo ba jẹ obinrin lo ni, t’ara nìkan lo maa mọ.

Nigba ti wọn bi boya ki awọn obinrin sa fun awọn ọkunrin ti wọn ba ni owo ju lọ, Gehgeh ni wọn le fẹ wọn ṣugbọn ki wọn fi owo wọn gbe awọn ọkunrin naa s’oke ti wọn ba fẹ ni ade l’ori.

Gehgeh to sọ ara rẹ ni oludasilẹ fasiti Gehgeh to ti n kọ awọn ọkunrin l’ẹkọ lori ọna a n gba na owo paapaa julọ to ba ti di ọrọ obinrin ni awọn imọran rẹ maa n saba fa ariyanjiyan lori ayelujara.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search