Mo Padanu Iṣẹ Nitori Mo Kọrin Pẹlu Lateef Adedimeji – Sola Allyson

Mo Padanu Iṣẹ Nitori Mo Kọrin Pẹlu Lateef Adedimeji - Sola Allyson

Gbajugbaja onkọrin ẹmi, Sola Allyson ti ṣaṣọloju bi pipe to pe oṣerekunrin Adedimeji Lateef sibi ọkan lara awọn eto to maa n ṣe ṣe ṣokunfa pipadanu iṣẹ nilẹ Amẹrika.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ kan, Allyson ṣalaye pe pasitọ kan ti ṣeto eeyan kan to fẹ pe oun fun iṣẹ nigba t’oun wa L’Amẹrika. O ni iṣẹ naa o jẹ t’oun nitori oun ati Lateef jọ k’ọrin papọ lori itage kan-naa.

Awọn amuludun mejeeji ni wọn ti jọ kọrin papọ lọpọ igba bii ọjọ-ibi Sola Allyson to ṣe l’ọdun to kọja, ti wọn si ṣafihan pe o ṣeeṣe ki awọn ẹlẹsin mejeeji le jọ wa ni alaafia.

Kikọrin pọ wọn lo ti fa ero oriṣiriṣi fun ọpọ ọdun pẹlu bi awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹ lu bi onkọrin igbagbọ ṣe le maa ba onkọrin musulumi kọrin pọ lori itage kan-naa.

Fọnran to ṣafihan ọrọ ti Allyson sọ yii lo ti fa ọpọ ariwisi lori gbigba ẹlẹsin keji mọra pẹlu bi ọpọ ṣe bu ẹnu atẹ lu pasitọ naa pe ko nifẹ ẹlẹsin keji, ti ọpọ si ni Ọlọrun kan naa ni gbogbo wa n sin, nitori naa, ki ẹnikẹni ma gbiyanju lati gbeja Ọlọrun.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search