Ajọdun Aṣa Yoruba: Ayẹyẹ manigbagbe ṣẹlẹ n’Ibadan!

Niṣe lero n rọ girọ-girọ, ti wọn n da bii omi, niluu Ibadan lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2025 ni papa iṣere Ọbafẹmi Awolọwọ Stadium eyi to wa lagbegbe Oke-Ado, niluu Ibadan, ni ipinlẹ Ọyọ, latari ayẹyẹ manigbagbe kan to waye niluu naa.

 

 

Iroyin ko to afojuba ni ayẹyẹ ọjọ naa, latari bi oniruuru awọn eeyan ja-n-kan ja-n-kan, awọn lookọ-lookọ nilẹ Ibadan, awọn ọba alaye gbogbo, awujọ awọn lóyè-lóyè, awọn oloṣelu, awọn oniṣowo, t’ọmọde-t’agba, t’olórí t’ẹlẹ́mù, to jẹ ọmọ bibi ilu Ibadan, awọn àrè ati alejo gbogbo lo peju pesẹ sibi aṣekagba to fakíki naa.

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ati akẹgbẹ rẹ lati ipinlẹ Bayelsa, Ọlọla-julọ Douye Diri, atawọn abẹṣin-kawọ alajumọ-ṣakoso wọn gbogbo lo wa nikalẹ.

Aka-i-ka-tan ni iran apewo to waye ni papa iṣere naa. Meloo la o ka ninu eyín adépèlé ni. Bi eegun ṣe n pidán, ti wọn n dárà, bẹẹ ni awọn ẹlẹgbẹ-jẹgbẹ n fi oniruuru aṣọ ibilẹ, aṣọ àjọdá ati imura àrímáleèlọ, àwòtúnwò, àwò-padà-ṣẹ́yìn ati oge àrànbarà yẹ́ ariya  ọjọ naa si.

Bo ba jẹ ti imura ati oge ṣiṣe ni, ṣe ti awọn to wọṣọ iṣembaye ni ka sọ ni, nibi tawọn agba ọkunrin ti ko si oriṣiiriṣii agbada nla nla, ẹwu ẹtu, san-an-yan ibilẹ, pẹlu fila abalaye to ṣe wẹku, abi tawọn obinrin ti wọn fi gele, ipele, iborun ati bata da bira, ti ẹgba ọrun ati tọwọ n dan bii digi, ti wọn n dá gọ̀jọgọ̀jọ ninu irisi to n dán gbinrin, pẹlu ẹwà ati ọ̀ṣọ́ to ṣafihan àṣà abalaye oniran-iran ati t’ode oni nilẹ Ibadan, nile Oluyọle.

O fẹrẹ ma si iru ijo ti ko waye tan lọjọ taa n wi yii, awọn ọmọge n ran bii okoto loju agbo, egungun ati awọn gende jo bata, wọn jo si ilu gangan, awọn kan jo si ṣẹkẹrẹ, ijo ajo-laagun, ijo awo-dami-ẹnu gidi, bi atẹwọ ṣe n ro lakọlakọ, bẹẹ ni orin ibilẹ ati ti igbalode gbode, ko tiẹ si agbo teeyan de ni tinu tode papa iṣere nla naa, ti onitọhun ko ni ri iran àwò-kan-sáárá wò. Ayẹyẹ naa rẹwa gidi, o jojunigbese, o si mu ki ori ọgọọrọ ọmọ Ibadan wu, idunnu han loju wọn fun apọnle ati iyi ti eto ọjọ naa mu wa, bi wọn ti n jẹun yala-yolo, bẹẹ ni wọn n fi oriṣiiriṣii ọti ẹlẹri-dodo ati ọti lile, bia ati nnkan mimu olomi-ọsan le e, faaji n ṣan patapata ni!

Ọjọ Satide ọhun ni aṣekagba ajọdun Aṣa ilẹ Ibadan, eyi ti wọn n pe ni Ibadan Cultural Festival lede eebo, ti ọdun 2025 yii waye.

Odidi ọsẹ kan gbako ni ayẹyẹ naa ti gbode kaakiri origun mẹrẹẹrin ilu Ibadan, ki wọn too fi adagba eto rọ si papa iṣere nla to wa l’Oke-Ado ọhun.

Lasiko ti Gomina Makinde n sọrọ, wọn fi oye Ọrẹ ilu Ibadan to fakọyọ (Outstanding Friend of Ibadan) da ọrẹ rẹ, Gomina Douye Diri lọla, bẹẹ ni Makinde ṣeleri pe pẹlu ayẹyẹ nla ọjọ naa, ijọba oun yoo tubọ mu ileri ati erongba rere rẹ ṣe lati ṣe atilẹyin fun igbelarugẹ aṣa ilẹ Ibadan ati kaakiri ipinlẹ Ọyọ lapapọ.

O tun ṣeleri pe gbogbo ipo, aaye ati ọwọ to tọ si awọn ori ade ọrun ilẹkẹ ni ipinlẹ Ọyọ lawọn yoo fun wọn, tori ọba lo ni aṣa, ọdọ wọn si ni ibujooko aṣa nilẹ Yoruba, awọn o si nii jẹ ko parun tabi mẹ́ẹ́rí rara.

O ni oun ti paṣẹ pe ki awọn onṣejọba oun pese awọn ọkọ bọginni bọginni to yẹ ipo ọba Olubadan ti ilẹ Ibadan fun un, bẹẹ lawọn yoo si pese nnkan irinsẹ to yẹ fun gbogbo ori ade yooku nipinlẹ Ọyọ.

Makinde dupẹ gidigidi, o ṣe sadankata fun ẹgbẹ CCII (Central Council of Ibadan Indigenes) ti wọn gbe eto nla yii kalẹ, o si kan saara sawọn ọmọ Ibadan ti wọn kọwọ ti eto alarinrin naa lẹyin.

Ka mu tẹgan kuro, manigbagbe gbaa ni ayẹyẹ Ajọdun Aṣa ilẹ Ibadan ti ọdun 2025 yii o!

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search