Gbajugbaja oṣerekunrin to ti ya sidi oṣelu bayi to n ṣ’oju ẹkun Surulere 1 nile igbimọ aṣofin t’ilu Eko, Desmond Elliot ti ṣalaye bi ọrọ ṣe ri lọdọ tiẹ lori rogbodiyan eleyi to waye nile aṣofin ọhun to fa ki awọn kan gbero lati yọ Abẹnugan ile aṣofin Mudashiru Obasa to si n ṣalaye idi to ṣe buwọlu iwe lati yọ l’oye.
Elliot lo ṣe alaye yii nigba to n fesi si ọrọ ti ọga awọn oṣiṣẹ nile iṣẹ aarẹ, Femi Gbajabiamila sọ pe iṣẹ fẹẹ bọ lọwọ oun latari iwadi to fi han pe Elliot mọ nipa idipampa lati yọ Obasa lori eto kan ti wọn pe si lori ẹrọ amohunmaworan.
O ṣalaye pe oun o si lorilẹede Naijira nigba ti ọrọ naa ṣẹlẹ nitori naa l’oun ṣe lero Aarẹ fọwọsi yiyọ abẹnugan naa. O tẹsiwaju pe ni ọjọ kẹtala oṣu kini, oun ati iyawo oun l’awọn jọ lọ silu oyinbo lati lọ sibi igbeyawo aburo iyawo oun nitori ile aṣofin wa ni isinmi ati pe orilẹede South Africa l’oun wa nigba ti ọrọ iyọniloye naa waye to si jẹ ohun iyalẹnu gidi f’oun.
Oṣerekunrin to ti di oloṣelu yii ṣalaye pe nigba t’oun maa fi de ọpọ awọn ẹgbẹ oun nile aṣofin ni wọn ti buwọlu iwe lati yọ Obasa loye ti gbogbo awọn si lero pe nkan ti Aarẹ fọwọsi ni ṣugbọn lẹyin oreyin ni Aarẹ pe awọn lati sọ pe kii ṣe ifẹ oun niyẹn to si ni k’awọn daa pada leyi ti gbogbo ọmọ ile aṣofin naa ṣe lẹsẹkẹsẹ.
Nigba to n fesi si ọrọ ti Femi Gbajabiamila sọ, Elliot ni o ya oun lẹnu gan pe ẹni to jẹ aṣaaju ati aladuroti f’oun le sọ nkan bẹẹ.
Rogbodiyan yiyọ Obasa ṣẹlẹ lọjọ kẹtala oṣu kini ọdun yii nigba ti ọpọ awọn ọmọ ile aṣofin gbimọ pọ lati yọ nigba to wa ni igbafẹ nilu oyinbo latari awọn ẹsun bii aṣilo agbara, aiṣe daadaa gẹgẹ bii adari, pipẹ de ijoko, ṣiṣe owo ile mọkumọku ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lẹyin eyi ni igbakeji rẹ Mojisola Meranda wọle gẹgẹ bi abẹnugan tuntun ati obinrin akọkọ ni ipo naa ko to di pe Obasa kọ iyọnipo naa pe ko ba ofin mu.
Eyi lo fa ti awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC ati Aarẹ da si nigbati ọrọ naa di yọnpọn yọnrin. Lẹyin eyi ni Meranda kọwe fiposilẹ ti wọn fi da Obasa pada sipo.