PELLER TIKTOK PA IYA RẸ L’ẸKUN NI GBANAGBA

Ọdọmọde irawọ ori ikanni TikTok nni, Habeeb Hamzat Adelaja ti ọpọ mọ si Peller n lo pa iya rẹ l’ẹkun ayọ ni gbangba walia. Ninu fọnran kan to’n ja ranyin-ranyin lasiko yii ti Peller fun ra rẹ fi si’ta l’ori ikanni TikTok rẹ lati ri Peller ati iya rẹ ninu ipo ti ko wọpọ.

N ṣe ni Peller f’ọwọ bo iya rẹ l’oju lati oke ile tan wa, wa si isalẹ. Iyalẹnu nla gbaa lo jẹ fun mama Peller t’ori ko l’ero oore yii ni’gba to wọ’le de kulẹ, bi ala gbaa lo jọ. Ọkọ bogini funfun, tuntun hanran ni ọmọ ologo naa ra fun iya rẹ, l’ariwo ayọ ba sọ. Ọkọ funfun balau Hyundai Santa FE ni Peller ra fun mama rẹ. Iya yii ko le pa ayọ rẹ mọ’ra, lo ba kun’lẹ to bu sẹkun gbaragada, ẹkun ayọ gbaa ni.

Ṣe wọn ni inu ẹni kii dun ka pa mọra, iṣẹlẹ ayọ yii ko gba omi nikan lẹnu iya Peller, o tun gba ọpọ iwure at’ọkan wa lati ẹnu iya naa si ọmọ rẹ. Dẹmu-dẹmu ni inu ọkọ ọlọyẹ naa ṣe. Bii inu mama yii ti n dun ni ọpọ awọn eeyan miran lati ọọkan naa n dunnu fun iya naa.

Peller ẹni to di gbajumọ lati ori ikanni TikTok to si n ri t’aje ṣe gidi nibẹ l’ọwọ yii lo dun iya rẹ ninu. Amọ ṣa, bi ọrọ yii ti jẹ ohun ayọ to, ko pẹ ko jina ni awọn miran l’ori tun beere pe ti baba nkọ abi awọn baba ko r’aye wa ni? Peller fun ra rẹ ko ku’nu, to n naa si n ṣe ibeere taani ninu wọn ni baba oun ṣaroye airi nnkan jẹ fun? Tobẹ jubẹẹ lọ, Peller ko kọ ibi ara si awuyewuye eyi, amọ ṣa ti oun ati iya rẹ ati awọn afẹnifẹre n yọ ayọ ọkọ tuntun lọ..

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search