PELLER TIKTOK GBIYANJU ATI WA ARA RẸ PA NINU ỌKỌ TUNTUN TO RA

Ori lo ko gbajumọ ọdọmọkunrin l’ori ikanni TikTok, Peller yọ ninu ewu ijamba ọkọ ninu ọkọ Mercedes tuntun to ra laipẹ yii. Ṣebi Peller, ṣaaju asiko yii, laipẹ rara lo ti kọyọ ayọ ọkọ tuntun to fi ṣe ẹbun opin ọdun fun ara rẹ.

Ṣadede ni fọnran kan to ti n kaakiri ori ayelujara l’ede eleyii Peller fun ra rẹ ṣe to ti n sọ awọn ọrọ to l’agbara latari ipo iporuru ọkan to wa. Peller ni fọnran pe oun yoo pa ara oun to si gbiyanju ati wa ara rẹ pa lẹsẹkẹsẹ ninu ọkọ to tin ṣe fọnran naa ṣugbọn ti ko ku.

Koko ohun to bi iporuru ọkan Peller yii si ni bi ọrọ ifẹ oun ati ololufẹ rẹ iyẹn Jarvis ti ṣe ni kan l’asiko yii to sa da bi pe opin ti fẹ de ba ọrọ ifẹ wọn.
“Gbogbo yin ẹ ṣeun, mo ni’fẹ yin, mo dupẹ!!! N o pa ara mi, mo fi orukọ Ọlọrun bura, (o bu s’ẹkun) wallahi ẹru ba mi (o n sun ẹkun tẹsiwaju) n ko fẹ pa ẹni kankan l’ara, mo kan fẹ ṣe eyi fun ra mi.” Wọn yii ni awọn ọrọ ti Peller n sọ pẹlu omije titi to fi wa mọto naa jaamu.

Ni bayii, bi awọn kan ti n pa ọmọkunrin yii dupẹ fun ẹyọ Ọlọhun ni awọn kan n pe olowo fi owo ra iku ati pe iṣẹ kii pa ni ayọ ni pa eniyan. Ero ti wa ni pe ki Oluwa o kọ Peller ati Jarvis mọ ṣe nini irin-ajo igbesiaye wọn.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search