Blessing C.E.O R’ogun Ẹjọ, Wọn Lo Purọ Gb’owo Ni

Gbajumọ afọrọlede ati aṣoju awọn ile-iṣẹ lori ẹrọ ayelujara, Okoro Blessing Nkiruka ti gbogbo eeyan mọ si Blessing CEO ni ajọ to n risi iṣowo kumọkumọ (EFCC) ti wọ dewaju ile-ẹjọ bayi lori ẹsun ikowo to to miliọnu mọkandinlaadọrin le ni ẹsun mẹẹdogun (₦69.15 million) jẹ.

Ajọ EFCC wọ de iwaji adajọ R.A. Oshodi ti ile-ẹjọ awọn ẹsun to yatọ nipinlẹ Eko lori ẹsun meji to da le pipurọ gba owo ati ole jija.

Gẹgẹ bi ajọ naa ṣe wi, o fi ọna eru gba owo lọwọ ile-iṣẹ Chiropractic Health Clinic Limited lori ile kan to puro pe oun l’oun ni to si gbe lẹ fun wọn lati lo fun ọdun marun eyi to jẹ irọ patapata lẹyin naa lo wọ owo naa s’apo ara rẹ.

Lẹyin ti wọn ka ẹsun rẹ sii leti tan ni Blessing ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun. Latari ẹbẹ naa, Adajọ Okezie wa ko ṣi wa ni agọ awọn EFCC titi yoo fi jẹ ẹjọ keji to ni niwaju ile-ẹjọ giga tilu Eko bẹẹ lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlogun oṣu keje ọdun yii lati j’ẹjọ lori gbigba beeli rẹ.

Ẹwẹ, ninu ẹjọ keji ti Blessing CEO jẹ loni niwaju ile-ẹjọ giga tilu Eko ni wọn ti gba beeli rẹ lori ẹsun ipuro gb’owo miliọnu mẹtala (₦13 million) to ni oun nilo lati wo aarun jẹjẹrẹ.

Eleyi lo waye lẹyin ti ọpọ awọn eeyan ati ajọ bii ajọ to n risi aarun jẹjẹrẹ lorilẹede Naijira (Nigeria Cancer Society) pe lẹjọ.

Ninu ọrọ kan ti ajọ EFCC fi lede lori itakun ibanidọrẹ Instagram wọn ni wọn ti ni Blessing wa niwaju ile-ẹjọ lori ẹsun mẹfa ọtọọtọ to da le pipurọ gb’owo.

Awọn olupejọ yii ni wọn l’awọn da’wo fun lẹyin to jade ṣe fọnran pe oun n ba ipele kẹrin aarun jẹjẹrẹ ọyan fa t’oun si nilo iranlọwọ ko to di pe aṣiri tu pe ayederu ni iwe to fi han f’aye ri.

Ti ẹ o ba gbagbe, ninu oṣu kẹta ni Blessing jade wa sọrọ pe oun n ba aarun jẹjẹrẹ ọyan fa to si ti wa ni ipele kẹrin bẹẹ lo beere fun iranlọwọ lọwọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria. Lẹyin eyi ni awọn dokita oriṣiriṣi ti wọn nimọ nipa aarun jẹjẹrẹ wa ja irọ pe ko ri bẹ.

Ọpọ awọn eeyan ni wọn kọwe ipẹjọ si ajọ EFCC leyi to fa ti wọn fi gbe.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search