Lẹyin iṣẹlẹ ijinigbe to waye si awọn akẹẹkọ ati olukọ ni ijọba ibilẹ Oriire ni agbegbe Ogbomoso ni ipinlẹ Ọyọ, oniruuru awọn gbajumọ lawujọ lo ti bẹrẹ si ni ke gbajare pe ki ijọba tete wa nnkan ṣe.
Yatọ fun awọn ipe to ti waye sẹyin lori ipo ewu nla ti eto aabo wa ni orilẹ-ede Naijiria, awọn akiyesi tuntun ati ikilọ lo ti n foju le’de fun ijọba lati ọdọ awọn ẹni igba oju mọ pe ki ijọba o tete ṣe giri lori amojuto eto aabo.
Gbajugbaja oṣere, Toyin Abraham kọ si ori ayelujara pe n ṣe ni ọkan oun gba ọgbẹ ti inu oun ko si dun rara si iṣẹlẹ ipaniyan, ikọlu ati ijinigbe to ti ṣan de ipinlẹ Ọyọ nitori ibaṣepọ oun pẹlu ipinlẹ naa ko kere nipasẹ ẹbi, aṣa ati ifẹ ti oun ni si awọn eniyan ipinlẹ naa. O kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi ti o f’ara gba, bẹẹ lo ki ijọba ipinlẹ Ọyọ fun ipa to ti ko ṣugbọn to tun beere fun igbesẹ gboogi lati doola awọn ti wọn jigbe naa layọ ati alaafia. “Ko tọ ki ọmọ kankan o ma bẹru ati lọ ile-ẹkọ nitori ewu, ko dẹ yẹ bẹẹ ki ọmọ orilẹ-ede Naijiria kankan o ma gbe ninu ifoya ewu ati aibalẹ ọkan. A ko ni sọ iwa ipa di ohun ti o tọ lawujọ wa, a o si tẹsiwaju lati ma s’ọrọ.”
Ẹwẹ, arẹwa oṣerebinrin, Kẹhinde Bankọle ni ti ẹ n pe ijọba ko gbọdọ pe iṣoro eto aabo ni igbiyanju awọn alatako lati ba ijọba lorukọ jẹ nitori gbogbo igba ni ẹmi n ṣofo, ijọba gbọdọ doju kọ iṣoro yii, “iyẹn gan-an ni ipolongo ibo.” O kesi ile-iṣẹ Aarẹ, oludamọran pataki lori eto aabo ati awọn miiran lati tete mu iṣẹ ṣe.
Ni ti Ruth Kadiri, gbajugbaja oṣere ati adari ere ni ti ẹ, o pe ijọba gbọdọ mu ọkan ninu mimu oju to ebo aabo l’odidi abi ki wọn o yọnda fun ilu gbogbo lati daabobo ara wọn.
Irawọ olorin takasufe, Jaywon ni ti ẹ tun ta si awọn akẹgbẹ rẹ pe wọn kọ lati kọ ibi ara nigba ti oun pariwo pe awọn agbẹbọn ati agbesunmọmi n ja awọn Okun ni ipinlẹ Kogi logun ṣugbọn ti wọn gba ara ta nigba ti o ṣẹlẹ ni ipinlẹ Ọyọ bayii.
Ọpọ awọn ilumọọka ni ìpele jipele miiran lo ti n bẹrẹ si ni ma lo anfaani ti wọn ni laarin ilu ati lori ayelujara lati pe fun atunṣe lẹka eto aabo nilẹ yii.