ỌGA BELLO NI BABA MI – BIGVAL JOKOTOYE, OṢERE TIATA

Irawọ oṣere Nollywood kan to fi igba kan mu’le si oke okun, ni orilẹ-ede Amẹrika to ti wa pada si’le bayii, Bigval Jokotoye lo ṣe ifọrọwọrọ l’ori eto kan l’ori ayelujara. Ni’bẹ lo ti tọka si bi iṣẹ tiata ṣe bẹrẹ fun gan-an ni pato ati bi ogbontarigi oṣere nni Adebayọ Salami ṣe jẹ baba fun-un.
Bigval ni ile’gbe ile-ijọsin ìyẹn Mission House ni oun gbe dagba to si fa bi oun ti ṣe jẹ onitiju eniyan ni ibẹrẹ ọjọ ti ko si ti tan l’ara rẹ.

feeb2a60-57c6-4e84-bfa8-7a3e06796031

Bẹẹ lo m’ẹnuba ijanikulẹ kan ti oun ko’ju ni’gba ti oun ṣẹ n wọ’nu iṣẹ ere, o pe ipa Ọranmiyan ni wọn ti pe oun yoo ko ninu iṣẹ naa ṣugbọn ti wọn pada gbọn oun yọ nipasẹ pe eniyan pupa ni Ọranmiyan ti oun ko si pupa ṣugbọn ti oun mọ pe awijare lasan ni botilẹjẹpe wọn fi ipa miran rọpo, pe ki oun o ṣe Ọba Alayemọrẹ kekere pẹlu awọn oṣere nlanla bi Iya Awẹro gẹgẹ bii oloye ti oun si fakọyọ to mu ki oloogbe Yọmi Ogunmọla o bun oun ni ẹẹdẹgbẹta (₦500) naira.
Ko tan si’bẹ, ko ṣai mẹnuba bi oun ṣe di ero Eko. O ni oko ere yii naa l’oun ti pade Iya Bisi Ogunde to jẹ aṣaraloge ni’bi iṣẹ naa to pe oun wa si Eko to si gba oun nitẹ.

Lẹyin naa lo tun ṣiṣẹ gba ọdọ awọn agba oṣere bii Lọla Idije, Remmy Shitta-Bey, Iya Awẹro ati bẹẹ bẹẹ lọ kọja ki oun to wa de ọdọ Ọga Bello.

Gẹgẹ bii Bigval ti wi “ọdun marun-un ni mo fi gbe l’ọdọ Ọga Bello ti wọn si da mi mọ ọmọ tọ. Yatọ fun baba to bi mi, Adebayọ Salami, Ọga Bello nikan ni mo tun ma n pe ni baba mi.”

Ibaṣepọ naa bẹrẹ ni ọjọ kan ti awakọ wọn ko si nitosi, ti iṣẹ si wa fun wọn ni agbegbe Mẹran, “bi mo ṣe gbe wọn lọ niyẹn lai wa ọkọ ri tẹlẹ ninu Eko.” Lati igba naa ni mo ti wa pẹlu wọn gẹgẹ bi wọn ṣe bi mi botilẹjẹpe oun to wu emi gan naa jọjọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search