Ilumọọka oṣerekunrin Emeka Ike ti fi erongba rẹ han lati dije dupo wọle aṣojuṣofin. Erongba yii lo fi lede ninu fọnran kan to n tan kaakiri ori ẹrọ ayelujara bayi ni Ike ti sọ pe oun fẹ dije lati ṣoju ẹkun Bwari/AMAC Federal Constituency nilu Abuja labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NDC.
Nigba ti wọn bii pe ki lo maa ṣe yatọ ti awọn ara agbegbe naa ba dibo yan, Ike ni to ba jẹ pe oun ti munu awọn ọmọ orilẹede Naijiria dun tẹlẹri, ni bayi asiko ti to lati ṣe ju atẹyinwa lọ lati di ọna mọ awọn ti wọn ro pe wọn lagbara.
O tẹsiwaju pe asiko ti to lati dide gba agbara ati ṣe atunto orilẹede Naijiria nitori ko yẹ k’awọn araalu maa bẹbẹ fun ohun to tọ.
Ike ṣafikun pe oun o binu si awọn oloṣelu rara nitori wọn ti fi han gbangba pe ẹmi awọn araalu ọ jọ wọn loju ṣugbọn oun n binu si awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn o ṣe nkan to yẹ. O wa rọ awọn eeyan lati lọ gba kaadi idibo wọn ni kiakia nitori iyẹn gan ni ariwo ta nilo lati pa lọwọ yii.
Emeka Ike to ti sun sẹyin diẹ nidi iṣẹ tiata lati bii ọdun melo kan sẹyin lo ti wa darapọ mọ awọn amuludun ti wọn fẹ kopa ninu oṣelu fun ilọsiwaju orilẹede Naijiria lapapọ.