TOYIN AIMAKHU BA ARA RẸ NI PATI (PARTY) AIROTẸLẸ

Sinima tuntun “Oversabi Aunty” lat’ọwọ gbajugbaja oṣere nni, Toyin Aimakhu Abraham lo ti pa biliọnu kan naira ni sinima l’asiko l’awọn ololufẹ rẹ ba da inawo oniyalẹnu si’lẹ fun-un fun aṣeyọri naa.

Mọmi Ire bi awọn miran ṣe ma n pe oṣere naa la ri ninu fọnran kan ninu aṣọ to d’ọsọ ati oju to gun rege, to n wọ’le si’nu gbọngan inawo kan. Lọgan to da’sẹ wọ’le ni ẹnu ya oṣere naa gba kọja sisọ, pati oniyalẹnu ìyẹn “surprise party” ni awọn ololufẹ rẹ ṣe fun lati fi ba da’wọ idunnu pe sinima rẹ ti pa biliọnu kan ni sinima.

gọrọ awọn eniyan ati ohun ti ko l’ero lo ganni ninu gbọngan ti kaluku ti wa ni imurasilẹ ti ojo orin naa si n bọ wọrọwọ. Toyin ti awọn miran tun mọ si World Best ni ko le pa idunnu ati iyalẹnu rẹ mọra, ti kosi r’aaye w’oju awọn ololufẹ rẹ pẹ, nitori bo ṣe n t’aju ri ikan, ni omiran naa tun yọju.
Ọgọrọ awọn ololufẹ oṣere yii ti wọn ma n da pe ni “Toyin Titans” lo ti wa da’wọ idunnu pẹlu gbajugbaja oṣere naa fun aṣeyọri rẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search