Baba Ilebaye BB9ja: Nitori Imukumu ati Iwakiwa Ni Mo Fi Da Sẹria Fun Ọmọ Mi

Lẹyin ti fọnran alawuyewuye kan jade sita, nibi ti olubori nigba kan ri ninu idije Ile Ẹlẹgbọn Agba (BB9ja House) ti orukọ rẹ n jẹ Ilebaye ti n sunkun pe baba oun lu oun bi ejo aijẹ, ti ọpọ awọn eniyan si bẹrẹ si ni tara lori ọrọ naa.

L’ọwọ yii, baba to bi Ilebaye ti bọ sita lati ṣe alaye bi ọrọ ti jẹ gan-an lootọ. Ninu ohun kan to jade lori ayelujara ni baba Ilebaye ti ko alaye ọrọ jade.

Gẹgẹ bi baba naa iyẹn Hon. Godson Okinawa ti wi. O ni awọn ayipada buruku to de ba aye Ilebaye lati igba to ti gbe igba oroke ninu eto BB9ja lo fa bi oun ti fọwọ ba ninu fọnran to di ariwo naa ti oun kii si ṣe baba buruku b’awọn kan ti n l’ero.

O jẹ ko di mimọ pe ọmọ ti oun dunnu si gidigidi ni Ilebaye jẹ ki okiki ati ọla BB9ja to sọ di nnkan miiran. To n mu imukumu; ko ẹgbẹ kẹgbẹ; na ina kuna laarin awọn iwa palapala miiran. Lara awọn ọrọ rẹ lọ bayii:

“Ni gẹrẹ ti Ilebaye di olubori ninu eto BB9ja tan, lo ba yawọ patapata. N ṣe lọ fi owo tun idi rẹ mọ, to si tun oju rẹ gbẹ pẹlu iṣẹ abẹ at’ẹwaṣe igbalode (cosmetic surgery).

“Ọrọ imọran mi ti wa koro buruku leti ọmọ mi, to si n mu mi bi ọta. Koda gan-an, o ti n mu egbogi oloro, l’eyi to ti fi koba aburo rẹ ọmọ kekerekunrin, ọdun merinla titi to fi yọ lẹnu ẹkọ. Ati pe, Ilebaye fun’ra rẹ a maa ṣe ijamba abi lu oun nigba miran ti oun ba gba lamọran gẹgẹ bii baba s’ọmọ, ti awọn apa irufẹ ikọlu bẹẹ ṣi wa lara oun.

“Ti mo ba ni ko f’owo ṣe oun gidi abi ran alaini lọwọ. Ko ni gbọ si mi lẹnu rara. Ẹgbẹ k’ẹgbẹ l’oun ko kiri.

“Mo tọrọ aforijin lọwọ gbogbo aye, e fori jin mi ati mọlẹbi mi. Ara ọmọ lo ta mi, n ko le woran ki aye ọmọ naa bajẹ lo jẹ ki n ṣe oun ti mo ṣe. Ẹ jọwọ ẹ fi ẹbi wa sinu adura.”

Oriṣiriṣi awọn eniyan ti ọrọ naa n dun lo ti bẹrẹ si ni fi ero wọn han lori ọrọ naa ti ọpọ wọn si n da Ilebaye lẹkun fun iwa buruku.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search