Awọn Pasitọ Ẹgbẹ Mi O Ma Da Nnkan Mọ, Olodo Oṣelu Lo Pọ Ninu Wọn

Awọn Pasitọ Ẹgbẹ Mi O Ma Da Nnkan Mọ, Olodo Oṣelu Lo Pọ Ninu Wọn

Gbajugbaja pasitọ kan ma re, ojiṣẹ Ọlọrun Fẹmi Emmanuel ti ijọ Living Spring Chapel International ti sọ ọrọ to da họwu-họwu si’lẹ l’agbo igbagbọ ati l’ori ayelujara gan-an paapaa.

Pasitọ yii ni ko fi ti ori amohunmaworan ile-iṣẹ TVC to wa ti gbogbo aye ti n wo ṣe, n ṣe ni ọkunrin ojiṣẹ Ọlọrun naa la ọrọ mọ’lẹ wankeke, to si kan abẹ ni’ko lai bikita.

Ninu ọrọ Pasitọ Fẹmi Emmanuel, baba naa ni ọpọ awọn aṣaaju ninu ẹṣin Kristẹni ni o da nnkan mọ to jẹ pe ẹsin oloṣelu ni wọn ma n tẹ’ju mọ l’ọpọ igba, lai bikita ni’pa bi wọn ti kun-oju-oṣuwọn to, l’eyi to si jẹ pe kii ṣe pe awọn gan-an wọ inu oṣelu de’bi ti oye rẹ yoo ti ye wọn daadaa.

Pasitọ ba tun wọ inu Bibeli lọ lati ṣ’akawe ọrọ rẹ, o ni iwe Roomu, ori kẹwaa : ẹsẹ keji wi bayii pe “Awọn ọmọ Israẹli lootọ wọn ni itara, ṣugbọn kii ṣe nipasẹ imọ.” Eyi to ja si pe awọn eniyan ni itara fun nnkan ṣugbọn ti oye rẹ ko ye wọn to.

Akawe yii gan-an ni Pasitọ Emmanueli fi pe “awọn eeyan mi, awọn pasitọ ẹgbẹ mi – iyẹn oluṣọ aguntan; awọn alabojuto apapọ iyẹn G.O lootọ ni wọn ni itara fun orilẹ-ede yii. Wọn ṣiṣẹ kara, wọn gbagbọ ninu rẹ, wọn si ni’fẹ rẹ gidigidi, ṣugbọn bo ba ti di ọrọ oṣelu bayii, ope lasan-lasan ni wọn jẹ, ti wọn ko da nnkan mọ.

Oluṣọ-Aguntan naa ba tun ṣe ibeere pe, “a n pe a fẹ oludije si’po aarẹ ti yoo jẹ Kristẹni, bawo ni’yẹn ṣe fẹ wa’ye nigba ti kosi awọn aṣoju to jẹ onigbagbọ iyẹn Kristẹni ninu ẹgbẹ oṣelu. Ẹ o le ri oludije to ka’ju rẹ bi ko ba si aṣoju to ka’ju rẹ. L’awọn ẹsẹ-kuku, l’awọn wọọdu, n jẹ a ni awọn eeyan ni’bẹ? Ba wo wa lo ṣe fẹ jẹ?”

Ojiṣẹ Ọlọrun naa tun tẹsiwaju pe “Awọn Kristẹni o si ni bẹ jare. Ẹ o si ni’bi ti wọn ti n ṣ’ofin abi ibi ti wọn ti n ṣe imuṣẹ ilana eto ijọba, ẹ kan n pa’riwo lati ori pẹpẹ. Eyi kan da bi ẹni to n ki’gbe l’ohun rara lati ẹyin odi abi ẹyin iganna niyẹn (ti ariwo rẹ ko ni de ibi to yẹ).”

L’aarin bi ifọrọwọrọ naa pẹlu oniroyin ti n lọ, Pasitọ Emmanuel ba tun mu orukọ Ọjọgbọn Yẹmi Ọsiinbajo, to jẹ Igbakeji Aarẹ tẹlẹ ri, to si tun jẹ oluṣọ aguntan bakanna lati ṣe apẹẹrẹ, o ni “ẹyin ẹ wo ọdun 2019, kii ṣe musulumi ati kristẹni l’asan ni wọn fa kalẹ o, musulumi ati pasitọ ni. Ọmọ-iya wa ati arakunrin mi. Pasitọ Ọṣinbanjo to jẹ olori pipe ẹda ati ẹni ti ọrọ da ṣaka l’ẹnu rẹ Amọ ṣa, bi ofin orilẹ-ede Naijiria ti ti laa ka’lẹ, ipo wo-isọ-de-mi l’asan iyẹn (spare tyre) ni igbakeji aarẹ jẹ.

O tẹsiwaju pe, “ki wa ni ohun ti awa kristẹni n beere fun? ipo igbakeji! Ere wo ni eyi yoo mu wa fun ijọ Ọlọrun? Kosi! Nitori ipo arọpo l’asan ni ipo igbakeji aarẹ, o da bi ọba to n reti ati jẹ l’asan ni.”

Oniroyin tun bi pasitọ yii l’eere ọrọ pe n jẹ awọn kristeni nikan ni Oluwa fi le ṣe akoso ilu abi jẹ adari rere, o ni rara o, pe ẹni to ni ibẹru Ọlọhun, ẹni to ṣe f’ọkan tan, ti yoo da bi baba fun gbogbo ilu lo ja ju.

O wa ko ọrọ nilẹ pe bi eniyan ti kaato si, bo ṣe ni ifọkantan si lo yẹ lati ma wo bo ba di ọrọ iyanni-sipo oṣelu.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search