MI O LỌ ILE-IJO (NIGHT CLUB) MỌ – DAVIDO

Gbajugbaja onkọrin Afrobeats, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido lo ti jẹ ko di mimọ pe oun ko naa ile-ijo (Night Club) mọ, ti eyi si yatọ si bi ọpọ ti mọ Davido tẹlẹ gẹgẹ gbajumọ amugborodun ati alafẹ.

Nigba to n s’ọrọ ni’bi eto ifọrọwanilenuwo kan to ṣe laipẹ yii pẹlu ile-iṣẹ l’ori ikanni YouTube ni olorin ti mẹnuba pe ọla, okiki ati iyi ti oun tete ni l’asiko to wa ni ọdọ langba lo sọ oun di ẹni to ma n paara ile-ejo nigba naa ṣugbọn ti mọlẹbi, isinmi ati agba ti n gba irufẹ igbesiaye naa kuro l’ọwọ oun.

Ẹwẹ, Davido ẹni to ṣẹṣẹ de lati ibi eto ami-ẹyẹ Grammy ti ko pada ja mọ l’ọwọ, to si dun awọn ololufẹ rẹ jọjọ lo tun ti sun siwaju kuro l’ori iyẹn to si n ba iṣẹ rẹ siwaju. Amọ ṣa Davido ni lilọ ile ijo ni ko ya si oun l’ẹsẹ mọ bi ti igba kan.

Ọgọrọ awọn ololufẹ lo ti wa n gba pẹlu Davido pe lootọ ni agba ma n gba oriṣiriṣi ohun l’ọwọ ẹni.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search