Gbajugbaja oṣere Nollywood nni, Rotimi Salami ti fi iha to kọ si ọrọ ṣiṣe iwadii lati mọ ojulowo baba ọmọ nipasẹ ayẹwo DNA. O jẹ ko di mimọ pe oun ko le kọ ọmọ silẹ latari pe ayẹwo DNA fihan pe oun kọ ni baba-ibi (biological father) ọmọ naa.
Salami lo fi ero rẹ han l’asiko to n kopa ninu ifọrọw’ọrọ kan to ṣe laipẹ yii pẹlu ile-iṣẹ iroyin BBC Yoruba. Nibẹ lo ti na nibẹ pe ọmọ ti oun ti n tọ bọ lati kekere, to si ti gbanju mọ oun ni baba ni oun ko le kọ silẹ rara koda ki ayẹwo DNA o fidi rẹ mulẹ pe oun kọ lo bi. “N o gba iru ọmọ bẹẹ t’ọwọ t’ẹsẹ.” O ṣalaye siwaju si pe, ko lẹtọ lati jẹ ki ọmọ kankan o jẹ ninu iya ẹsẹ aimọdi botilẹ wu ko mọ, ti ifẹ oun ko si ni dinku s’ọmọ naa nitori ti ko l’ẹsẹ kankan lọrun.
Salami fi kun pe l’aarin oun ati iya ọmọ naa ni ọrọ wa ti ko si kan ọmọ rara, koda “Ọmọ naa yoo ma jẹ orukọ mi lọ titi lai, ti yoo si tun ri mi bi baba pẹlu, nitori ọmọ naa kọ lo ṣẹda ara rẹ wa’ye. Emi ati iya ọmọ naa ni ọlọrọ.” Ẹwẹ, iwoye awọn onwoye l’ori ayelujara ṣe ọtọtọ l’ori ọrọ ti Salami sọ yii, awọn kan n pe ẹnu dun ro’fọ ni ọrọ ti Salami sọ bẹẹ ni awọn kan ni gbẹwu dani ọkunrin ni, awọn miiran sí gbagbọ pe ọmọ akin ni Salami jẹ fun ipinu naa.