Eemọ, Ẹ Wa Wo Awọn Jankoriko (Bandits) Ti Wọn Mu Nitosi Papakọ Ofurufu Ilu Akurẹ!

Eemọ, Ẹ Wa Wo Awọn Jankoriko (Bandits) Ti Wọn Mu Nitosi Papakọ Ofurufu Ilu Akurẹ! Ha-hin lo n ṣe ọpọ awọn olugbe agbegbe papakọ ofurufu (airport) ilu Akurẹ nitosi adugbo Ẹlẹyọwo nilu Akurẹ nipinlẹ Ondo nigba ti wọn kẹfin awọn afurasi jankoriko (banditi) ti l’agbegbe papakọ ofurufu.

Lana ọjọ Aiku Sunday ni ajọ FAAN to n ṣ’amojuto awọn papakọ ofurufu gbogbo nilẹ yii lati akata Ọgbẹni Henry Agbenire to jẹ agbẹnusọ wọn fi atẹjade ọrọ sita pe awọn afurasi jankoriko banditi mẹrin (4) ni ọwọ ba lana ode yii lẹyin odi papakọ ofurufu naa.

Alaye ọrọ ni pe awọn ara ilu kan lo kọkọ kẹfin awọn afurasi jankoriko banditi naa ti wọn le awọn agbẹ bọ lati inu oko, ti wọn si le wọn titi de papakọ ofurufu, leyi to mu ki awọn ti iṣẹlẹ naa ṣ’oju wọn koro ta awọn eleto aabo ni olobo.

Pẹlu ifọwọsowọpọ awon ikọ eleto aabo bi ọlọpa, ologun ati ti ẹṣọ alaabo papakọ ofurufu naa ni wọn fi mu awon afurasi jankoriko mẹrin mu.

Ajọ FAAN wa rọ awọn ararinajo, awọn olugbe agbegbe naa ati awọn ẹni ọrọ kan gbogbo lati ma foya rara nitori ohun gbogbo wa ni sẹpẹ.

Ẹwẹ, ipinlẹ Ondo wa ninu awọn ipinlẹ ni ẹkun iwoorun guusu (Southwest) ti ikọlu si eto aabo ti wọpọ julọ, leyi to fa bi ọpọ l’ori ayelujara ṣe n ta’ra poro pe ki idajọ ododo o wa’ye l’ori awọn afurasi naa.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search