Gbẹgẹdẹ Gbina, Peter Obi Lọ Ki Malami Ni’le Lẹyin To T’ẹwọn, Ni Wọn Ba Kede Ogun

Gẹrẹ lẹyin ti ile-ẹjọ gba ki wọn o gba beeli Abubakar Malami ti ṣe Agbef’ọba Agba ati Alakoso tẹlẹ ri fun eto idajọ l’asiko iṣakoso Aarẹ anaa, Oloogbe Muhammadu Buhari, ti wọn si daa si’lẹ kuro l’ọgba itunirọ lati wa ma ti’le jẹ’jọ ni Peter Obi to jẹ oludije si’po Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour ninu eto idibo ọdun 2023 ṣugbọn to ti wa ninu ẹgbẹ oṣelu ADC l’ọwọ yii pẹlu Malami ṣe abẹwo si. Abẹwo naa lo ti bi oniruuru awuyewuye l’agbo oṣelu ati l’ori ayelujara l’ọwọ yii.

Malami ati awọn kọọkan ninu mọlẹbi rẹ lo n ka’wọ pọn’yin ro’jọ l’ori ẹsun lilu owo ara ilu ni ponpo ati lilọwọ ninu ohun to ni ṣe pẹlu igbesunmomi. Ti ọrọ ẹjọ rẹ si ti n lọ lati bi igba diẹ s’ẹyin ṣugbọn ti ile-ẹjọ yi yọnda lati gba oniduuro mọlẹbi ati awọn eniyan rẹ pẹlu miliọnu l’ọna igba naira (₦200m) ẹni kọọkan.

Yatọ fun awọn ero to jẹ alatẹle rẹ to wa ki kaabo nigba to dari pada si ile rẹ ni’lu Abuja ati awọn ọmọ ẹgbẹ ADC kọọkan ti wọn ti ṣe abẹwo si, ọkan pataki ni Peter Obi jẹ ninu awọn to ti wa Malami si’le lati nnkan anaa ode yii. Botilẹjẹ pe pupọ oun ti wọn jọ sọ ni ko han si’ta ṣugbọn to jẹ pe abẹwo jẹ lati ṣugba Malami to n f’oju wi’na ẹjọ l’ọwọ. Ko tan si’bẹ, Malami l’asiko to n ba awọn alatẹle rẹ s’ọrọ ni’pa ohun to n lọ jẹ ko di mimọ pe oṣelu to gbona giri ṣẹṣẹ bẹrẹ l’akọ ni bayii, ti oun ko si ni ja’wọ ninu gbigba akoso ijọba ipinlẹ Kebbi laipẹ.

Amọ ṣa ọpọ awọn ololufẹ Peter Obi ati awọn ẹni ọrọ kan miran lo koro oju si abẹwo Peter Obi ti wọn si n tọka pe, o jọ pe aguntan Peter Obi ti n ba aja rin, to ṣi ṣeeṣe ko jẹ igbọnsẹ buruku. Gbajugbaja ajaf’ẹtọ ati oludije tẹlẹ ri si’po aarẹ, Ọmọyẹle Ṣoworẹ juwe Obi gẹgẹ bi ṣago ti n bu’go.

Ẹwẹ, ọgba bi ile-ẹjọ ti gba iyọnda (beeli) Malami ni awọn alatẹle gomina tẹlẹ ni’pinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai to n naa n koju oun to f’ara pẹ ti Malami n beere pe ki wọn o da ẹni ti wọn naa si’lẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search