Iṣẹlẹ kayefi gba lo wa’ye niluu kan ti wọn pe ni Ozoro, iyẹn ni ipinlẹ Delta. Ohun eemọ kan lo ma wa’ye ni’bẹ. N ṣe ni wọn l’awọn n ṣe ọdun Ifipa-ba-ni-lo-pọ, bẹẹ wọn ko mu ọrọ yii ni awẹwa rara. Ootọ ni pe awọn ọdọ ilu naa kọọkan l’ọkunrin lo fọn si’ta ti wọn si bẹrẹ si ni f’ọwọ ba eyikeyi obinrin to ba wa ni arọwọto wọn. Eyi to si pada jẹ pe ọgọrọ awọn ọdọmọbìnrin l’agbegbe naa ni wọn f’ọwọ ba abi ṣe aṣemaṣe pẹlu wọn. Fọnran ati awọn aworan to jẹ jáde lati ibi ayẹyẹ ọdun onikayfi naa lo tu aṣiri iṣẹlẹ naa sita f’aye ri, eleyii ti ọgọrọ awọn eniyan ko foju ire wo paapaa julọ l’ori ayelujara.
Ẹwẹ, Ọba alayeluwa nilu Ozoro naa fi aidunnu rẹ han sí iṣẹlẹ naa, to sì n pe fun ki idajọ ododo o waye. L’ọwọ bayii, ile-iṣẹ ọlọpa nipinlẹ Delta ṣalaye pe awọn ti mu awọn afurasi melo kan l’ori iṣẹlẹ naa ti iṣẹ iwadii dẹ ṣi n tẹsiwaju.
Oniruuru awọn eniyan lo ti wa m’ẹnuba iwoye wọn l’ori iṣẹlẹ yii ti ko si yọ awọn ilumọọka na si’lẹ.