O kere tan awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi Fulani to to ẹgbẹrun lọna ọgbọn ni wọn n ṣọṣẹ l’ẹgbẹ l’ẹgbẹ pẹlu ọmọ ẹgbẹ to to laarin mẹwa si ẹgbẹrun gẹgẹ bi iwadi kan ti ajọ United States Commission on International Religious Freedom fi lede.
Iwadi naa fi han pe awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi yii buru ju awọn ti wọn n jija ẹsin lọ bẹẹ lo n ṣafihan bi awọn ọdaran Fulani naa ṣe n ṣọṣẹ ni ẹkun aarin gbungbun ati ẹkun guusu l’eyi to ti ṣokunfa ki ọpọ sọnu nigba ti awọn ogunlọgọ ti ba awọn ikọlu naa lọ.
Ajo naa tẹsiwaju pe bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹlẹsin kristẹni ni wọn koju, awọn musulumi naa ti faragba nibi awọn ikọlu, iṣekupani ati ijinigbe naa.
Iwadi naa fi kun pe ọpọ awọn ẹgbẹ naa ni wọn o ni olori ṣugbọn wọn maa n ṣe ikọlu kiri paapaa julọ si awọn igberiko.
O kere tan awọn eeyan miliọnu kan le ni ẹsun mẹta ni awọn ọdaran naa ti ṣi nidi kuro ni ẹkun aarin gbungbun pẹlu ikọlu oriṣiriṣi laarin ọdun 2025 si ọdun 2026 ni ipinlẹ Benue ati Plateau.
Nipari, ajọ naa sọ pe ti awọn ijọba apapọ ati tipinlẹ o ba ṣe nkan to yẹ lati rii pe aabo to peye wa f’awọn ọmọ orilẹede Naijiria, o ṣeeṣe ki ikọlu naa tẹsiwaju.
Iwadi yii waye lasiko ti orilẹede Naijiria n ba eto aabo to mẹhe ja to si n fa ibẹrubojo fun gbogbo araalu.