Ẹgbẹ oselu All Progressives Congress (APC) ti gbe idajọ gbe’le ẹ alainigbedeke (indefinite suspension) kalẹ fun ẹni to jẹ ekan l’ara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, ni ijọba ibilẹ Bonny ni ipinlẹ Rivers, Dagogo Fubara. Igbeṣe ẹgbẹ oselu APC yi lo wa’ye l’ẹyin ipade ikọ awọn agbagba ẹkun naa, eleyii ti Richard Ibani ti ṣe Alaga ijoba ibilẹ Bonny ṣaaju ikọ naa, latari iwa aitọ eleyii ti Fubara wu tako iwe ofin egbe.
Fubara lo kọ iwe ip’ẹjọ tako ẹgbẹ oṣelu APC lati pa’gi di’na ipade apapọ ti ẹgbẹ oṣelu naa n ti da’jọ rẹ s’ọna nitori bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe kuna lati fa a kalẹ fun ipo igbakeji alaga ti yoo soju ẹkun guusu ninu idibo oloye apapọ ẹgbẹ oṣelu wọn.
Ninu iwe ip’ẹjọ rẹ, Fubara ṣalaye bii oun ti se san owo to le ni miliọnu marun-un naira (over ₦5m) fun ẹgbẹ lati le fa oun k’alẹ fun ipo igbakeji alaga, ṣugbọn ti ẹgbẹ kọ jalẹ lati ṣe ẹtọ, to si n beere fun ki ẹgbẹ o san owo gba-ma-binu ọgọrun miliọnu naira (₦100m) fun oun.
Ẹwẹ, ẹni ti o jẹ alaga ẹkun ijọba ibilẹ Bonny ṣ’apejuwe iwa fubara gẹgẹ bii eyii to tako ofin ati ilana ẹgbẹ oṣelu APC, to si tun ta’buku ẹgbẹ wọn.
“Fun idi eyii, ile koko n tagbe ti ko si l’ọjọ tabi gbedeke” gẹgẹ bi Ibani ti wi.