Adije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NDC, Peter Obi lo ti beere fun owo biliọnu marun-un ati ẹbẹ itagbangba gẹgẹ bii itanran lọwọ oṣerekunrin to ti di oloṣelu bayi, Kenneth Okonkwo lori ẹsun ibanilorukọ jẹ latari awọn ohun to sọ nibi ifọrọwanilẹnuwo kan lori ẹrọ amohunmaworan.
Obi to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Anambra lo ti leri pe bi Okonkwo o ba ṣe oun maa wọ de iwaju ile-ẹjọ ti o si ṣeeṣe k’oun beere ju bẹẹ lọ nile-ẹjọ.
Ninu lẹta kan ti awọn agbẹjọro Obi ti agbẹjọro agba Alex Ejesieme (SAN) lewaju wọn fi lede ni wọn ti f’ẹsun kan Okonkwo pe o pa irọ to jina si ootọ mọ Obi to si ba lorukọ jẹ nigba to wa lori eto naa leyi ti ọpọ awọn iwe iroyin si gbe lẹyin to tan ka.
Gẹgẹ bi o ṣe wa ninu lẹta naa, wọn ni Okonkwo sọ lori eto naa pe Obi ati awọn agbagba ẹgbẹ oṣelu NDC ni ẹkun guusu ila-oorun sọ fun awọn ti wọn ni lọkan lati dije dupo ile aṣojuṣofin gbọdọ san miliọnu mẹwa naira (₦10million) ni riba fun awọn agba ẹgbẹ ati ẹgbẹ lẹyin ti wọn ba ti san owo fọọmu iferongba han.
Awọn agbẹjọro naa ni Okonkwo tun sọ pe oun ni ẹri pe Obi lo ṣe akojọpọ awọn adije dupo ẹgbẹ naa funra rẹ to si gba owo lọwọ awọn eeyan ni oke okun pẹlu awọn iwa ọdaran to wu pẹlu awọn agba ẹgbẹ.
Wọn ni gbogbo awọn ẹsun yii lo ṣafihan Obi gẹgẹ bi ẹni to n gba riba, alailootọ, alọnilọwọ gba ati ẹni to n ṣe owo ilu kumọkumọ ti ko si ri bẹ bẹẹ ni wọn ni gbogbo ọrọ naa n ba iwa ati orukọ rere ti Obi ni.
Awọn agbẹjọro naa wa fun Okonkwo ni ọjọ meje lati ko ọrọ ẹ jẹ ko si tọrọ idaraji ẹṣẹ ni ita gbangba
Nigba to fesi si lẹta naa, Okonkwo ti fi awọn aworan oriṣiriṣi to n ṣafihan ọrọ to ni o waye laarin oun ati Ohaegbu to ni o jẹ ẹri ọrọ t’oun sọ lori ifọrọwanilẹnuwo naa.
O ni gẹgẹ bii araalu ati agbẹjọro, oun l’ẹtọ lati ṣaṣọloju iwa ọdaran kankan bẹẹ lo ni oun o tii ka lẹta naa, t’oun ba ka tan l’oun maa fesi gẹgẹ bi o ṣe tọ.