Ẹgbẹ́ olóṣèlú All Progressives Congress, APC, ti kéde owó fọ́ọ̀mù fún àwọn olùdíje ṣáájú ìdìbò gbogbogbò t’ọdún 2027. Nínú Àtẹ̀jáde kan eleyii tó ní ètò iṣẹ́ àti àkókò fún ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027 ti Akọ̀wé Ìṣètò Àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà, Sulaimon Arugungu, buwọ lu ní ọjọ́ Satide ni ọrọ náà tí jáde.
Ìpinnu yìí jẹ́ ìgbésẹ̀ kan nínú imura ẹgbẹ́ náà fún eto ìdìbò tó ń bọ lọna. Gẹ́gẹ́ bí atẹjade ṣe fihàn, àwọn tó fẹ́ díje fún ipò Ààrẹ yóò san owó ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà(₦100,000,000), nígbà tí àwọn tó fẹ́ di gómìnà yóò san aadọta mílíọ̀nù náírà(₦50,000,000).
Àwọn olùdíje sí Ilé aṣòfin àgbà yóò san ogún mílíọ̀nù náírà(₦20,000,000), àwọn ilé aṣojú ṣòfin yóò san mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà (₦10,000,000), nígbà tí àwọn ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ yóò sì san mílíọ̀nù márùn-ún náírà(₦5,000,000).
Wọn tẹ síwájú pé owó yìí jẹ́ àpapọ̀ owó fọ́ọ̀mù láti fi èróngbà hàn àti fọ́ọ̀mù ìdìbò nigba tí títà àwọn fọ́ọ̀mù náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní ìparí oṣù Kẹrin, ọdún 2026.
Wọ́n ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ yìí jẹ́ ọ̀nà láti ṣètò ìdìbò abẹ́lẹ̀ tó yanranti ṣáájú ìdìbò gbogbogbò.