Ile-iṣẹ ọlọpa ẹka tipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iwadi l’ori igbiyanju ati ṣeku pa alaga ẹgbẹ oṣelu Accord nijọba ibilẹ Osogbo, Asimiyu Ajibọla.
Ajibọla ni awọn afurasi agbebọn kan yin nibọn lalẹ ọjọru l’agbegbe MDS nilu Oṣogbo to si n gba itọju lọwọ bayi ni ile iwosan ti ile-ẹkọ fasiti Ọṣun.
Agbẹnusọ fun ẹka ile-iṣẹ ọlọpa naa, Abiọdun Ọjẹlabi sọ ninu atẹjade kan to fi lede loni pe ikọlu naa waye ni nkan bii aago mẹwa ku iṣẹju mẹwa nigba ti awọn ọdaran agbebọn meji ti wọn wa lori ọkada deede yinbọn mọọ l’ojuna ati gbẹmi lẹnu rẹ.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe gbe, awọn ọlọpa dahun si ipe pajawiri naa, wọn gbe Ajibọla lọ sile iwosan nibi to ti n gba itọju lọwọ bẹẹ ni wọn bẹrẹ iṣẹ iwadi lati fi ọwọ ofin mu awọn oniṣẹ laabi ọhun.
Ọjẹlabi ni ọga ọlọpa nipinlẹ naa Ibrahim Gotan ti pe fun iwadi ọrikiniwin lẹsẹkẹsẹ lati mu awọn ti wọn ṣiṣẹ naa ki wọn le f’imu kata ofin.
Ile-iṣẹ ọlọpa naa wa rọ awọn araalu lati f’ọkan balẹ, ki wọn si ṣe iranwọ pẹlu iroyin to le jẹ ki wọn tete ri awọn ọdaran naa mu bẹẹ ni wọn fi wọn lọkan balẹ pe awọn maa ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe idajọ ododo jade.
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa bẹẹ ni wọn n pe fun iwadi ọrikiniwin lati f’oju awọn aṣebi han.
Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna fun iroyin ati ilanilọyẹ Kọlapo Alimi buwọlu, ijọba ni Ajibọla n gba itọju lọwọ ni ile iwosan ti UNIOSUN. O ni ọkan lara awọn ti wọn wa ninu ọkọ naa sọ pe awọn n bọ lati agbegbe MDS nigba ti awọn agbebọn naa ṣina ibọn bo ọkọ ki awọn to sa wọ ile-iṣẹ ọlọpa ẹka ti Dugbe ti awọn ọdaran naa si f’ẹsẹ fẹ.
Kọmiṣọna naa wa rọ awọn ẹṣọ alaabo lati ri pe wọn mu awọn oniṣẹ laabi naa ki wọn si f’oju ba ile-ẹjọ.