Saheed Oṣupa Forin Bu Seyi Makinde Nibi Ipolongo Ẹgbẹ APC Nibadan

Gbajugbaja olorin Fuji, Saheed Oṣupa, loni, fi orin bu gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, nibi eto ikede erongba ati di oludije si ipo gomina fun Oloye Sarafadeen Alli ninu ẹgbẹ oṣelu APC to waye loni nilu Ibadan.

Obitibiti ero lati kọrọkọndu ipinlẹ Ọyọ lo korajọ si ori papa iṣere kan to wa ni agbegbe adugbo Yemẹtu nilu Ibadan, bẹrẹ lati nnkan aago mọkanla owurọ nibi ti gbajugbaja oloṣelu ati ọmọ Ile Aṣofin Apapọ lati ipinlẹ Ọyọ, Amofin Sharafadeen Abiodun Alli ti kede erongba rẹ lati dije du ipo gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.

Nibi eto yii ni awọn olorin Fuji bii Alhaji Rashidi Ayinde Merenge; Alhaji Saheed Oṣupa; Alh Abass Akande Obesere ti kọrin. Bi wọn ti n ki Aṣofin Alli ati awọn oloṣelu ẹgbẹ APC to wa nibi eto naa ni wọn sọ ogulutu ọrọ nipasẹ orin si awọn ẹgbẹ miran, paapaa julọ, ijọba Gomina Ṣeyi Makinde ti inu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Bi awọn olorin naa ti n da orin, lojiji ni Oṣupa kọ orin bayii to n beere pe “Ta lo mu were wa ṣe olori wa? 3.0 irọ lasan.” Botilẹjẹ pe Oṣupa ko darukọ Gomina Makinde ni pato ṣugbọn ti ọrọ naa ko ṣoro tu rara nitori awọn afiwe to foju han gedegbe ni.

Lọwọ yii, awọn kan n ṣe ibeere pe n jo yẹ ki awọn amuludun o ma polongo ibo abi ṣe egbe fun ẹgbẹ oṣelu kankan ni gbangba, bẹẹ ni awọn miran n ṣe eemọ pe abi Oṣupa to gba ẹbun ọkọ tuntun bọginni lọwọ Gomina Makinde tun kọ mọ lo n fẹnu ṣata rẹ ati ijọba rẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search