Atiku 2027: Awamọ mi leyii, Lẹyin Ọdun 2027 N Ko Dije Mọ

Igbakeji aarẹ tẹlẹ ri, Atiku Abubakar ti jẹ ko di mimọ pe ti idibo gbogbogboo ọdun 2027 to n bọ lọna ni yoo jẹ igba ikẹyin re ti yoo gbiyanju lati du ipo aarẹ ni orilẹ-ede Naijiria.

Atiku lo kede eyi laṣalẹ anaa lasiko ifọrọwọrọ to ṣe pẹlu ile-iṣẹ amohunmaworan Arise. Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe ibo ọdun 2027 to n bọ ṣe pataki si oun gidi gan nitori oun yoo ti wa ni ọgọrin ọdun (80 years) nigba naa.

Atiku ẹni ti ijade ọdun 2027 yoo jẹ igba keje ti yoo gbiyanju lati jẹ aarẹ orilẹ-ede yii. O ti dije pẹlu awọn oloṣelu miiran bi M.K.O Abiọla; Goodluck Jonathan; Muhammadu Buhari; ati Bọla Tinubu. Ẹwẹ, Atiku tun fikun pe, lati ọdun 1999, ẹkun Guusu orilẹ-ede Naijiria ti lo ọdun to pọ ju ti ẹkun Ariwa lọ, leyi to mu ki erongba rẹ lati dije jẹ eyi to tọna.

Awuyewuye ti n lo lori ẹrọ ayelujara bayi latari …

Awọn afurasi agbebọn ni wọn ti ji awọn arinrin-ajo …

Siwaju si, nigba ti wọn bi leere, Atiku ko sọ taara boya yo ṣe atilẹyin fun Peter Obi toun naa ni ireti lati dije ṣugbọn to jẹ ko di mimọ pe oun ṣetan lati gbaruku ti ẹnikẹni ti ẹgbẹ oṣelu ADC to wa lọwọ yii ba fa kalẹ, yala nilana ifẹnuko abi idibo.

Ni ipari, o jẹ ko di mimọ pe oun ni ijakulẹ lori bi iṣakoso iṣejọba Aarẹ Bọla Tinubu ṣe kuna patapata, amọ ṣa ti Oludamọran Pataki si aarẹ, Bayọ Ọnanuga ti fi esi ọrọ ranṣẹ si Atiku loni.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search