Ajọ to n ṣakoso ere idaraya l’agbaye (World Athletics), ti kọ ibeere elere ori ọdan fun orilẹ ede Naijiria, Favour Ofili, lati yi orilẹ ede ti yoo maa ṣoju kuro lati Orilẹ ede Naijiria si Turkey. Ofili lo fẹ fi Naijiria silẹ latari awọn adojukọ to koju pẹlu bi wọn ṣe n ṣeto ere idaraya ni orilẹ ede yii ati ipa to ti n ni lori iṣẹ rẹ.
Ajọ naa ṣalaye pe awọn fagile ibeere Favour latari pe orilẹ ede Turkey fi ibeere awọn elere-ije pupọ ranṣẹ ni igba kan naa eyi mu ki o da bii pe wọn n pe awọn elere idaraya wa lati awọn orilẹ-ede mii.
Ajọ naa tẹsiwaju pe ti wọn ba fọwọ sii, ó le tapa sí awọn ofin ere idaraya ati pe o ṣe pataki ki awọn elere idaraya ni ibaṣepọ gidi pẹlu orilẹ-ede ti wọn fẹ ṣoju, kii ṣe nitori owo tabi anfaani nikan. Latari ipinnu yii, Favour Ofili ko ni le ṣoju Orilẹ ede Turkey ninu idije agbaye ṣugbọn o ṣi le ṣoju orilẹ ede Naijiria to ba fẹ.
Nigba ti wọn ni fesi, Ajọ to n ri si Ere idaraya ni orilẹ ede Naijiria (Athletics Federation of Nigeria) ti sọ pe awọn ṣetan lati gba Ofili pada sinu ikọ to n ṣoju orilẹ ede yii. Lọwọ yii, ko tii han ibi ti Ofili fẹ ṣiṣẹ fun bi o tilẹ jẹ pe aaye wa fun lati bẹbẹ fún ayipada ọkan.