Osimhen Wa Lara Awọn Ti Wọn Gbe Ogo Naijiria Ga L’oke Okun – Obi

Adije dupo Aarẹ tẹlẹri labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party (LP) Peter Obi ti ki agbabọọlu orilẹede Naijiria to tun gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Galatasaray, Victor Osimhen ku oriire iṣẹ takuntakun to ṣe ninu ẹgbẹ agbabọọlu Galatasaray eyi to mu wọn lewaju ti wọn si gbe ife Turkish Süper Lig title.

Osimhen lo mi awọn leemeji ọtọọtọ lati fun Galatasaray ni ami ayo to mu wọn lewaju ninu idije naa.

Ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ X rẹ ni Peter Obi ti ni oun darapọ mọ awọn ololufẹ Victor Osimhen lati ba dawọ idunnu gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn n ṣe bẹbẹ l’oke okun paapaa julọ fun bo ṣe ko ikọ Galatasaray jẹ ti wọn fi gba ami ẹyẹ ọhun.

Obi gboriyin fun agba ọwọ iwaju fun ikọ agba ọjẹ ilẹ wa iyẹn Super Eagles fun suuru, ikoraẹninijanu ati ẹmi ati ṣe rere to ni. O fikun pe arikọṣe rere ni Osimhen jẹ fun ọpọ awọn ọdọ lorilẹede yii to si n jẹ ki wọn n’igbagbọ pe pẹlu iṣẹ takuntakun ati ifọkansi wọn maa m’oke laye.

Obi wa fi anfaani naa tẹnumọ pe o ṣe pataki fun wa lati k’owo le ẹka ere idaraya lorilẹede Naijira nitori ipo ti ẹka ere idaraya wa ko daa to pẹlu bi a ṣe ni awọn ti wọn mọṣẹ wọn n’iṣẹ lorilẹede yii.

Gẹgẹ bi Obi ṣe sọ, o ni orilẹede Naijiria ni awọn ti wọn dantọ bii Victor Osimhen ti wọn n wa anfaani lati gbe ogo orilẹede Naijiria yọ ṣugbọn wọn nilo awọn adari rere. O fikun pe oun nigbagbọ pe o ṣeeṣe lati ri idagbasoke kaakiri gbogbo ẹka.

Ni ipari ọrọ rẹ, Obi ki Osimhen ku oriire to si n gba l’adura fun pe yoo tubọ maa gboro si nidi iṣẹ bọọlu rẹ l’agbaye.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search