Awọn afurasi agbebọn ni wọn ti ji awọn arinrin-ajo kan, pẹlu awọn akẹkọọ ti wọn n lọ kọ idanwo abawọle ile ẹkọ giga (JAMB) gbe, ninu ikọlu tuntun ni Ipinlẹ Benue. Iṣẹlẹ yii tun ti mu ibanujẹ ati iberu ba ọpọ awọn eeyan nipa aabo l’orileede Naijiria.
Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ l’opopona Makurdi si Otukpo, nibi ti awọn oniṣẹ laabi naa ti da ọkọ akero kan duro ni alẹ. Ọpọ ninu awọn to wa ninu ọkọ naa jẹ awọn akẹkọọ ti wọn n lọ kọ idanwo JAMB.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe awọn afurasi agbebọn naa di ọna, wọn si fi ipa daa ọkọ naa duro, lẹyin naa ni wọn ko ọpọ awọn arinrin-ajo naa lọ sínu igbo to wa l’ẹgbẹ ọna ṣugbọn diẹ lara wọn ri aaye sa.
O kere tán, awọn arinrin-ajo mẹrinla (14) ni wọn gbe lọ, bo tilẹ jẹ pe a ko tii mọ iye awọn ti wọn ko gangan. Awọn Ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadi lati ri awọn oniṣẹ laabi naa mu ki wọn si doola emi awọn ti wọn jigbe. Iṣẹlẹ yii ti mu ibanujẹ ba ọpọ eniyan, paapaa julọ nitori pe awọn akẹkọọ ni ọpọ nínú àwọn ti wọn ko naa.
Awọn ara ipinlẹ Benue ti pe fun aabo to peye pẹlu iṣọ l’awọn oju ọna fun awọn arinrin-ajo nigba ti awọn alaṣẹ ni rawọ ẹbẹ si awọn araalu pe ki wọn ni suuru, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro bi wọn ṣe n ṣiṣẹ lati gba awọn ti wọn jigbe silẹ.