Funkẹ Akindele: Emi O Lọ Ṣọọṣi Mọ

Ilumọọka oṣere, Funkẹ Akindele ti ọpọ mọ si Jenifa jẹ ko di mimọ pe oun kii lọ si ile-ijọsin mọ nitori pe aworan oun ni awọn eniyan yoo ma ya, ti wọn yoo si tun ma fi oun ṣe iran wo.

Gbajugbaja oṣere yii lo sọ eyi ninu fọnran kan l’ori ayelujara nibi to ti wa ni ile idana, to ti n fọ eyin l’oni ọjọ Aiku Sunday. Ninu fọnran naa lo ti tọrọ gafara pe oun ko lọ si ile-ijọsin mọ nitori oju gbogbo to ma n pọ lara oun.

Dipo bẹẹ, o jẹ ko di mimọ pe, l’ori ayelujara (online) ni oun ti n darapọ mọ isin nitori ti o san ju ki oju gbogbo wa lara rẹ ninu ile-ijọsin lọ.

Jẹnifa lo ti kun awọn ilumọọka miran bii awọn ibeji olorin, Psquare ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn ti pa lilọ ile-ijọsin ti nitori idi kan abi omiran.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search