Adije dupo Aarẹ tẹlẹri labẹ asia ẹgbẹ Oṣelu Labour Party, Peter Obi ati Gomina tẹlẹri ni Ipinlẹ Kano, Rabiu Kwankwanso ti fi ẹgbẹ Oṣelu African Democratic Congress (ADC) silẹ bayi lati lọ darapọ mọ Ẹgbẹ Oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC) gẹgẹ bi a ṣe ri ninu fọnran kan lori ẹrọ ayelujara. Eyi lo waye lẹyin ti Obi kuro ninu Ẹgbẹ Oṣelu ADC nitori oun to ṣapejuwe gẹgẹ bii idarudapọ toun aigbọra ẹni ye to n ṣẹlẹ ninu Ẹgbẹ ọun.
Ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ X rẹ lo ti ṣalaye pe ipinnu yii tẹlẹ ọpọlọpọ ironu ati ẹdun ọkan to ba oun lori bi ọrọ oṣelu Orilẹede Naijiria ṣe ri. O ṣalaye pe niṣe ni oṣelu Orilẹede Naijiria n fi ojoojumọ di pẹta si pẹlu bi idunkokomọni, aisi aabo to peye, ifurasini ati ṣiṣe keeta ti ṣe gbokun mọ awọn Oloṣelu eyi to si n ba iṣejọba tọkantọkan jẹ.
O tẹsiwaju pe oun ti koju ọpọlọpọ ibẹnuatẹ lu ti ko ye ati ifungunmọ lawọn agbọn oṣelu toun ti darapọ mọ tẹlẹ nitori oun n wa awọn ti ironu wọn papọ pẹlu toun lati ṣe atunṣe to tọ si orilẹede Naijiria.
Bayo Ọnanuga & Peter Obi
Obi ṣalaye pe kikuro toun kuro ni ẹgbẹ oṣelu ADC kii ṣe nitori ija laarin oun ati awọn ti wọn n ṣakoso Ẹgbẹ Oṣelu naa. O ni ipinnu oun ko ṣẹyin awọn ija oṣelu ti ko l’opin eyi to n ba ẹgbẹ naa ja ati ẹjọ to wa nile-ẹjọ to ti fa ki wọn ma gbaju mọ oun to n lọ nilu.
O wa ni oun o fi tipatipa le ipo ni dandan nitori igbega ati idagbasoke Orilẹede Naijiria lo jẹ oun logun nitori oun nigbagbọ pe Naijiria tuntun ṣeeṣe.
Ipinnu Obi lati fi ẹgbẹ Oṣelu ADC silẹ ti wa fa ọpọlọpọ ibẹnuatẹ lu lati ọwọ awọn jankanjankan ninu oṣelu bii Oludamọran Pataki fun Aarẹ lori Ọrọ Iroyin ati Ọgbọn Inu, Bayo Ọnanuga.
Nigba to n fi ero ọkan rẹ sita lori ipinnu Obi lati kuro ninu ẹgbẹ Oṣelu ADC, Ọnanuga ni Obi nifẹ lati maa tẹlẹ ọna to rọrun eleyi si maa fa iparun fun. O ni nitori ko to lati koju awọn toku ti wọn maa jade dipo Aarẹ lo ṣe fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ. Onanuga ni ki awọn eeyan ma gbọ awọn idi ofege to sọ nitori idi to ṣe lọ ni pe ko le koju Amaechi ati Atiku lati jade gẹgẹ bi Oludije ẹgbẹ oṣelu ADC. O ni Obi nifẹ lati maa bẹnu atẹ lu ijọba lai yẹ ara rẹ wo. O wa pari ọrọ rẹ pẹlu kiki Peter Obi kaabọ sinu Idijẹ Ọdun 2027.