Ajafẹtọ ọmọ-niyan ati adije dupo aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijira, Omoyele Sowore ti ke si Ile-iṣẹ Ọlọpa ilẹ wa lati fi awọn mẹta ti wọn fi kele ofin gbe latari awọn ọrọ ibani lorukọ jẹ ti wọn sọ nipa ẹni to jẹ Alaga Ile ifowopamọ UBA, Tony Elumelu silẹ.
Ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ Facebook rẹ loni ni Sowore ti jiyan pe fifi ọrọ sita lori ipo igbeyawo ẹni to lorukọ lawujọ kii ṣe ẹṣẹ to le fa gbigbeni tabi titini mọle. O ni ẹṣẹ naa ko kọja ohun ti eeyan le yanju labẹ ofin ti ko si nilo a n fi t’ọlọpa si rara.
O tẹsiwaju pe, fun idi eyi Ile-iṣẹ Ọlọpa gbọdọ tu awọn eniyan naa silẹ ni kiakia. Ọrọ ti Sowore sọ yi jẹ jade lẹyin ti Ile ifowopamọ UBA jade lati wa sọrọ pe irọ to jina si ootọ ni iroyin to n ja rọnyin rọnyin pe, Oga Agba Ile-iṣẹ naa Tony Elumelu ati Iyawo rẹ Awele ti jawe mi o ṣe mọ fun ara wọn.
Ninu atẹjade kan ti ẹni to jẹ Olori lẹka ipolowo ọja ati ikede, Alero Ladipo buwọlu ni Ile ifowopamọ naa ti ṣapejuwe iroyin naa gẹgẹ bi ofege ati iro patapata ti awọn kan fẹ fi ṣi awọn araalu lọna ati lati banilorukọ jẹ.
Ile ifowopamọ naa wa fi da awọn araalu loju pe ọrọ naa ti wa lakata awọn agbofinro leyi to si ṣokun fa ki wọn fi kele ofin gbe awọn mẹta kan ti aje ọrọ naa ṣi mọ lori. Wọn wa ṣe ikilọ fun gbogbo eeyan ati awọn agbọn ti iroyin naa ba wa lati ye pin kiri ki wọn ma baa ṣe s’ofin.
Ọrọ yii ti wa fa ariwisi oriṣiriṣi bayi lori ọrọ ti ẹnu gba, ẹsun ibanilorukọ jẹ ati paapaa julọ ipo ti awọn agbofinro wa ninu ọrọ naa.