Ogbontarigi oṣere nni, Dele Odule ti awọn miiran mọ si “Baba Ijẹbu” lo ti tu aṣiri nla kan nipa igbesiaye rẹ.
Lori eto ifọrọwọrọ kan ti ogbontarigi oṣere yii ṣe laipẹ yii pẹlu ile-iṣẹ amohunmaworan ori ayelujara kan lo ti tu aṣiri naa pe oun ti fi igba kan lọ na posi oun ka’lẹ nigba ti ireti a ti jẹ nnkan nidi iṣẹ tiata pin.
Odule ṣalaye pe ni asiko naa, oun ko kuku ṣe aisan ṣugbọn ti ireti tan fun oun patapata, ati ọkan ati ẹmi oun rẹwẹsi sinu ọgbun aini’reti.
Ogbontarigi oṣere nni, Dele Odule
O tun jẹ ko di mimọ pe l’ọjọ ti oun gba ọdọ oni posi lọ, ogbontarigi irawọ oṣere miiran, Ẹbun Oloyede ti ọpọ mọ si “Ọlaiya Igwe” tẹle oun lọ, ti o si n sun ẹkun kikoro.
Siwaju si, Odule ṣalaye pe oun to fa aini’reti naa ko yẹ lẹyin pe gbogbo nnkan duro daari fun oun, ti awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn jọ pari ile-ẹkọ si ti n gbe nnkan ire ṣe, ti eyi si mu oun gba pe ireti ti pin.