O Ma Ṣe! Iru Iku Wo Lo Pa Okiki Adeshina Onitiata?

Ibanujẹ ṣ’ode paru lana ọjọ Aje (Monday) fun awọn onitiata nilẹ yii, paapaa julọ lẹka ti ede Yoruba nigba ti iroyin iku ọkan ninu wọn – Okiki Adeshina Oshin ti ọpọ mọ si “Jamọnlẹ” lu’gboro pa.

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere tiata (TAMPAN) Bọlaji Amuṣan “Baba Latin” lo kede iku irawọ oṣere yii l’ori ikanni Instagram to si n kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi oṣere naa ati gbogbo onitiata lapapọ lori ipapoda ẹni wọn.

Jamọnlẹ ko to ja’de l’aye ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ l’ọjọ kinni oṣu kẹfa ni ori ti kọ ko yọ ninu ewu ijamba ina ni oju-ọna marosẹ Eko si Ibadan ni nnkan ọdun mẹrin sẹyin.

Awọn onitiata akẹgbẹ rẹ ati awọn ololufẹ miiran ti bẹrẹ si ni fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si mọlẹbi oṣere yii.

Okiki Adeshina to jẹ ọmọbibi ilu Okeho ni ipinlẹ Ọyọ lo gbajumọ gẹgẹ bi oṣere, alawada, ati agbesinima jade.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search