Ibanujẹ ṣ’ode paro l’agbo awọn amuludun, ti gbogbo nkan si pa lọlọ l’aarin awọn oṣere latari iroyin iku gbajugbaja oṣere, Alex Ekubo to jade laye loni ọjọ Iṣẹgun Tuesday (12/05/2026) latari aisan jẹjẹrẹ ẹdọ (liver cancer) to ti wọ ipele kẹrin.
Awọn oṣere akẹgbẹ rẹ bii Funke Akindele, Bolanle Ninalowo, ati Godwin Nnadiekwe lo kede ipapoda arẹwa oṣerekunrin naa, ti wọn si n sọ iha ti wọn kọ si oṣere naa ati iru ibaṣepọ ti wọn ni sẹyin.
Alex lo jade laye ni ile-iwosan kan ni ilu Eko lẹni ogoji (40) ọdun lẹyin ọpọ oṣu to ti dubulẹ aisan.
Kayeefi nla ni ọrọ iku Alex jẹ paapaa julọ pẹlu pe o ti n ṣe aisan fun igba pipẹ ti ko si ni oore-ọfẹ lati kopa ninu ere kankan, koda awọn abala ibikan n pe aisan naa le to bẹẹ gẹẹ ti oṣere naa ti ṣe eto pinpin ogun rẹ silẹ.
Okiki Alex Ekubo lo bẹrẹ si ni kan nigba to ṣe ipo keji ninu idije ẹwa Mr Nigeria ni ọdun 2010, to si pada wa kopa ninu oriṣiriṣi awọn sinima olokiki bii “Merry Men; Sugar Rush; Fate of Alakada; Devil in Agbada; The First Lady” ati bẹẹ bẹẹ lọ.