Adije dupo aarẹ tẹlẹri labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party (LP) Peter Obi ti sọ pe ọdun mẹrin gẹgẹ bi aarẹ fun saa kan ti to ti awọn ọmọ orilẹede Naijiria ba dibo yan oun gẹgẹ bi aarẹ koda ki wọn gbe ibọn si oun lori.
Obi sọ eyi nibi fọnran kan to jẹ jade ninu ifọrọwanilẹnuwo kan lori ẹrọ amohunmaworan nibi to ti sọ pe ki nkan le to, saa kan pere l’oun maa lo gẹgẹ bi aarẹ.
Obi, to ti fi igba kan jẹ gomina ipinlẹ Anambra wa bẹnu atẹ lu awọn iṣẹjoba to wa l’ode yii paapaa julọ l’agbọn eyawo ati bi nkan ṣe n f’ojoojumọ gbowo lori si to si n sọ pe orilẹede Naijiria n koju iṣoro to l’agbara gidi l’asiko yii.
Obi lo jade lati dije dupo aarẹ ni ọdun 2023 to si ṣe ipo kẹta lẹyin Aarẹ Bola Tinubu ti igbakeji aarẹ tẹlẹri, Atiku Abubakar.
Ẹwẹ, nigba to n fesi si ọrọ Peter Obi, oludamọran pataki fun aarẹ lori iroyin ati ọgbọn inu, Bayo Ọnanuga tanna wo iwa Obi latẹyin wa leyi to fi le sọ pe oun maa kuro lori oye lẹyin saa kan.
Ọnanuga ni ka tibi irin-ajo Obi nidi oṣelu wo, pẹlu bi o ṣe leri leka lati ma kuro ninu ẹgbẹ APGA to gbe wọle gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Anambra nigba naa to si ṣe gbogbo ileri, o pada kuro bẹẹ lo ṣi n lọ lati ẹgbẹ kan si mii.
O tẹsiwaju pe, ẹni to ba gba Obi gbọ pe saa kan pere ni yoo lo, ko si nkan ti onitọun ko le gbagbọ. O fikun pe Obi kii ṣe ẹni ti eeyan le fi ojo ọrọ rẹ gbinka nitori bi o ṣe n fi ori ahọn ba awọn ẹgbẹ oṣelu ṣe naa ni awọn adehun rẹ ko ṣe ju ori ahọn lọ.
Ti ẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹta oṣu yii ni Peter Obi ati Rabiu Musa Kwankwanso ti o ṣeeṣe ki wọn jọ dije pọ, kuro ninu ẹgbẹ oṣelu ADC lo sinu ẹgbẹ oṣelu NDC.