Gbajugbaja oṣere binrin nni, Foluke Daramola-Salako ti ya sidi oṣelu gẹgẹ bo ṣe ti gba fọọmu iferongba han labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC lati dije dupo ninu ile aṣojuṣofin.
Foluke lo sọ eyi di mimọ lori itakun ibanidọrẹ Facebook rẹ nibi to ti fi aworan ibi to ti di fọọmu naa mu ni igbaradi fun idibo ọdun 2027.
Oṣerebinrin naa lo n gbero lati ṣoju ẹkun Oshodi-Isolo Federal Constituency 1 leyi to si ti kede rẹ tẹlẹ f’awọn ololufẹ rẹ.
Ninu ọrọ ipolongo rẹ, Foluke jẹjẹ lati ṣe atilẹyin fun awọn ofin to maa ṣe iranwọ fun awọn oṣiṣẹ ti wọn ba fi ibo gbe oun wọle bẹẹ lo n rọ awọn eeyan agbegbe Oshodi-isolo lati ni afojusun.
Nigba to n ba awọn eeyan to fẹ ṣoju sọrọ, Foluke ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bii iransẹ fun awọn eeyan t’oun ṣoju to si n gba l’adura pe ki Ọlọhun gbe wọn ga. Lakotan, Foluke wa beere fun ifọwọsowọpọ lati gbe agbegbe naa ga.
Foluke Daramola-Salako lo bẹrẹ ṣiṣe ni ọdun 1998 to si ti farahan ninu awọn sinima oriṣiriṣi. Yatọ si eyi, o tun jẹ ajafẹtọ ọmọ-niyan.
Nibayii, Foluke naa ti wa lara awọn amuludun ti wọn ti jade lati gbapoti idibo ṣaaju idibo ọdun 2027 to n bọ lọna.