Tinubu Fi Olasunkanmi Tegbe Lati Ibadan Jirọ Adelabu Gẹgẹ Minisita Fun Ọrọ ohun Amuṣagbara

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti yan Ọgbẹni Joseph Tegbe gẹgẹ bi Minisita fun oun Amuṣagbara nilẹ wa pẹlu bi o ṣe n duro de aṣẹ lati Ile Igbimọ Aṣofin Agba. Oludamọran pataki fun Aarẹ lori Iroyin ati Ọgbọn Inu, Bayo Onanuga lọ sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi lede.

Iyansipo naa lo ti wa niwaju Ile Aṣofin Agba Ilẹ wa bayi ki wọn le bojuwo lati mọ boya o yẹ nipo naa. Iyansipo Tegbe yii lo waye lẹyin ti Adebayo Adelabu kọwe fiposilẹ lati dije dupo Gomina ni Ipinlẹ Ọyọ.

Tegbe to jẹ ọmọ bibi Ipinlẹ Ọyọ bii ẹni to ṣaaju rẹ nipo naa lo ni iriri to le ni Ọgbọn ọdun nibi ẹka ọrọ aje ati atunṣe inawo nidi iṣẹ ijọba ati ti aladani. Lọwọlọwọ bayi, Tegbe ni Oludari ati Aṣoju Orilẹede Naijiria ati Orilẹede China lori ilọsiwaju ajọṣepọ to dan mọran laarin awọn Orilẹede mejeeji.

Atẹjade naa wa tẹnpẹlẹ mọ pe iyansipo Tegbe wa ninu erongba Ireti Ọtun ti iṣejọba to wa lode duro le lati le mu ayipada rere ba idakureku ina mọnamọna ki oun ọtun le ṣẹlẹ fun gbogbo mutumuwa.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search