Ija Nla N Bọ Laarin Gbajabiamila ati Desmond Elliot

Abenugan tẹlẹri fun ile aṣoju-ṣofin orilẹ-ede Naijiria, Fẹmi Gbajabiamila to tun wa ni ipo Ajirọba iyẹn olori oṣiṣẹ lọọfisi si Aarẹ Bọla Tinubu lọwọ yii lo ti t’ẹnu bọ ọrọ lori ibaṣepọ oun ati gbajugbaja oṣere to ti di oloṣelu, Desmond Elliot to tun jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko to n ṣ’oju ẹkun idibo Surulere 1.

Ninu fọnran kan to ti lu igboro pa bayii ni Gbajabiamila ti n ṣalaye ọrọ ẹnu rẹ loni ni ibi ipade pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC tọrọ kan ni pinlẹ Eko.

Gbajabiamila jẹ ko di mimọ pe “diẹ lo ku ki ọrọ Desmond Elliot yọ oun ni iṣẹ lọdọ aarẹ” latari bi Aarẹ ti ṣe beere nipa Elliot lọwọ oun (Gbaja) booya lootọ ni Elliot si jẹ ọmọ rere to ṣee fọkan tan.

Gẹgẹ bii Gbajabiamila ti wi “Aarẹ pe mi sinu ibi ikawe rẹ, to si bi mi nipa Elliot boya oun naa wa ninu awọn ọlọtẹ to gbero lati yọ Hon. Mudasiru Obasa iyẹn Abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ Eko kuro nipo rẹ l’ọdun 2025 ṣugbọn ti mo sọ fun aarẹ pe ko jẹ jẹ bẹẹ, ti ọrọ naa si jẹ kayefi fun aarẹ naa pẹlu pe Elliot ko le ṣe bẹẹ”

Abẹnugan ile aṣoju-ṣofin orilẹ-ede Naijiria tẹlẹ ri ọun tun sọ siwaju si pe oun pe Elliot lati fidi ipa rẹ ninu ọrọ naa mulẹ ṣugbọn ti o taku pe oun (Elliot) ko lọwọ nibẹ rara. Lẹyin eyi ni Gbajabiamila beere pe ki Elliot ko lọ ṣe afọmọ ọrọ naa ni itagbangba, iyẹn ni pe ko ṣe ikede pe oun ta kete si igbiyanju kankan lati yọ Ọbasa nipo Abenugan Eko ṣugbọn ti Elliot kọ lati ṣe bẹ.

Dipo eyi, Gbajabiamila ni ọga agba ajọ otẹlẹmuyẹ DSS lo pe oun lẹyin ọjọ diẹ pe ewu n bẹ, pe ajọ wọn ri olobo pe oun Gbajabiamila gan-an lo wa ni idi ọtẹ yiyọ Abẹnugan Ọbasa nipo l’Eko. Gbajabiamila ni kayefi nla ni eyi jẹ fun oun.

L’ọwọ yiii, ibi ti ija wa to si le buru jọjọ ni pe Gbajabiamila ko fẹ ki Aṣofin Elliot o pada wa mọ lati dije nitori awọn ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin ṣugbọn ti Elliot naa ko fẹ gba rara.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search