Ilumọọka aṣoju awọn ile-iṣẹ to tun jẹ ọmọ gbajugbaja oṣere binrin Iyabo Ojo, Priscilla Ojo ti ṣaṣọ loju bii awọn ara ilu ọkọ rẹ Juma Jux ṣe lero pe okobo ni nitori pe ko ni iyawo ati ọmọ ni ọmọ ọdun marundinlogoji pẹlu gbogbo owo ati okiki to ni.
O ni wọn bẹrẹ sii fura si latari pe gbogbo awọn ọrẹ ati olorin bii tiẹ ni wọn ti bimọ ti oun ko si bi pẹlu pe o ti fẹ awọn obinrin loriṣiriṣi.
Priscilla sọ eyi nibi ifọrọwanilẹnuwo kan to ti n ṣalaye ohun ti oju rẹ ri ko to di pe awọn bimọ ninu oṣu kẹjọ ọdun to kọja. O tẹsiwaju pe lẹyin ti awọn bimọ gan awọn kan lero pe ilana ati loyun ode oni ni awọn gba loyun ọmọ naa. O ṣalaye pe ọkọ oun jẹ ẹni to maa n ko ara ẹ nijanu ni gbogbo igba.
Ọdun to kọja ni Priscilla ati gbajugbaja olorin lorilẹede Tanzania, Juma Jux ṣe igbeyawo lorilẹede Naijira ati Tanzania ri wọn si bimọ ninu oṣu Kẹjọ.