Ọrọ Ẹsun Agbere Laarin Iyawo Frank Edoho ati Chike Ma Ti Da Ayelujara Ru

Lati nnkan ọjọ diẹ sẹyin ti iroyin jade pe gbajugbaja olorin olohun-arẹdodo, Chike ati Sandra to jẹ aya gbajumọ agbohunsafẹfẹ ati atọkun eto “Who Wants to be a Millionaire?” Frank Edoho n ba ara wọn da ifẹ ifẹ ikọkọ ni onikaluku ti bẹrẹ si ni jẹ ọrọ naa lẹnu bii guguru.

Awọn amuludun to fi mọ awọn ara-ilu lo ti bẹrẹ si ni wi ọkan abi meji lori iṣẹlẹ naa. Bẹẹ si ni awọn eniyan ko ye gbe oniruru fọnran ati awọn ọrọ ti Frank ti sọ sẹyin jade, leyi ti ọpọ wọn jọ mọ oun to n ṣẹlẹ.

Yatọ fun eyi, ọpọ awọn eniyan lo ti bẹrẹ si ni kọ abi lo awọn orin Chike, ti ọpọ wọn si jẹ orin ifẹ kọja tẹlẹ.

Amọ ṣa, lẹyin ọpọ awuyewuye lọtun losi, Sanra iyẹn aya Frank Edoho tẹlẹ rii naa ti jade lati fọ igba yanga lori ọrọ naa.

Ninu ọrọ rẹ, o jẹ ko di mimọ pe Frank gan-an ni alaida ati alaimoore eniyan nitori gbogbo bukata ati inawo idile wọn pata ni oun n gbe botilẹjẹ pe aya ni oun jẹ.

Siwaju si, Sandra ṣalaye pe Frank gan-an ni oju rẹ kii gbe ibi kan, to si fi ẹsun kan-an pe ọpọ igba lasiko ti oun wa ninu oyun akọkọ ni ọkọ oun ma a lọ ba ti awọn obinrin miran lai wẹyin wo abi bikita rara. Koda lasiko ti oun ni oyun ẹlẹẹkeji, ọkọ oun – Frank pe ki oun yọ oyun naa nitori oun ko ṣetan lati ṣe baba ọmọ lasiko naa nitori awọn obinrin miiran to fi mọ awọn oninabi to n ko kiri.

Ati pe gbogbo nnkan ati inu kan ni oun fi ba Frank lo, to fi mọ riran iya rẹ ni orilẹ-ede Amẹrika ṣugbọn ti gbogbo eyi ko da Frank duro ibajẹ.

Lọwọ yii, oriṣiriṣi awọn eniyan to fi mọ awọn gbajumọ lo fi ẹnu kun ọrọ naa, lara wọn ni Wumi Toriola; Flavour Nabania; Oye Myke, awọn miiran bii Kunle Rẹmi si lo ẹna lati gbe ero ti wọn jade. Bi awọn kan ti bu Frank, ni awọn miiran ni Chike lo ṣe oun to buru, bẹẹ ni awọn miiran pe iyawo gan-an ni oloju komu-olọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search