Bi Ebi Ṣe N Pa Yin Ti Ẹ O R’orun Sun Bẹẹ Gẹlẹ Lo N Ṣe Emi Naa – Aarẹ Tinubu

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lo ti sọ loni pe bi awọn atunṣe si ọrọ aje ti iṣejọba oun n ṣe lọwọ to n fa inira yii ko se lori awọn ọmọ orilẹede Naijiria nikan nitori oun gan ti padanu orun bẹẹ l’oun n ru nitori inira ti awọn atunṣe naa mu lọwọ.

O sọ eyi nibi to ti n gba tikẹti idije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC. Nigba to n ba awọn agbaagba ẹgbẹ ati alatilẹyin rẹ sọrọ ni gbọngan Bola Tinubu International Conference Centre to wa nilu Abuja lẹyin to gbegba oroke nibi idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu naa lati dije fun ipo aarẹ lẹẹkeji pẹlu ibo to le ni miliọnu mẹwa, Aarẹ ni gbogbo oun ti awọn ọmọ orilẹede Naijiria n koju latari awọn atunṣe yii pata lati bii ọdun mẹta sẹyin l’oun naa n faragba nibẹ.

O ṣalaye pe oun mọ nkan ti oju n ri lati ṣe atunṣe si orilẹede to ti fẹẹ daru tan t’awọn ba.
Aarẹ ni bi ẹnikẹni ba ti padanu orun ki wọn mọ pe oun gan o le sun bẹẹ ti ẹnikẹni ba ti ru ki wọn mọ pe oun naa ti ru. O tẹsiwaju pe ṣugbọn ni gbogbo igba l’oun ma n ranti pe ni ọdun 2022 ti oun beere fun iṣẹ naa, gbogbo awọn eeyan ni wọn gbaruku ti oun to fi jẹ ṣiṣe nitori naa oun gbọdọ ṣe.

Nigba to n gba iwe iyansipo lati dije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Aarẹ dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ fun pe wọn tun ka oun yẹ lati ṣoju wọn.

O ni niṣe l’oun farabalẹ wo eto idibo abẹle naa to si jẹ pe bo ṣe lọ kaakiri awọn ipinlẹ jẹ koriya fun oun paapaa julọ bi ko ṣe si ija tabi gbọnmisi-omi-o-to kankan.

Tinubu lo n ibo miliọnu mẹwa le ni ẹsun mẹsan lati bori ẹnikan ṣoṣo to jade tii iyẹn Stanley Osifo to ni ibo ẹgbẹrun lọna mẹrindinlogun le diẹ kaakiri awọn ijọba ibilẹ ẹrinlelaaadọrin o le ni irinwo to wa lorilẹede Naijira.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search