Eyi Ni Idi Ti Mo Ṣe Fi Awọn Ẹyin Mi Pamọ – Ashmusy

Amuludun lori ẹrọ ayelujara Amarachi Amusi ti ọpọ eeyan mọ si Ashmusy ti jade wa sọrọ nipa idi to ṣe gba ọna imọ sayẹnsi lati fi awọn ẹyin to n d’ọmọ lara obinrin tiẹ pamọ titi di igba to ba ṣetan lati bẹrẹ sii ṣ’abiyamọ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan lo ti ṣalaye pe oun ṣe bẹ nitori oun nifẹ si ṣiṣe abiyamọ gan to si wun oun lati gbe ọmọ jo l’ọjọ iwaju.

O ni oun ṣe ipinnu yii lẹyin ti oun ba ijakulẹ pade nibi awọn ibaṣepọ t’oun l’ero pe yoo pari si jijẹ lọkọlaya ṣugbọn ko ri bẹẹ.

O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe oun ti ri nisinyi pe ọpọ awọn ọkunrin o ni ọkan lati jẹ ọkọ koda ki wọn ṣe daadaa nibẹrẹ wọlewọde naa. O ni eleyii lo wa jẹ ki ọkan oun ṣi si pe oun le ma tete ri ọkọ gẹgẹ bi ọkan oun ṣe fẹ l’oun ṣe ṣe bẹẹ lati ma ni idiwọ nigba t’asiko ba to.

Ashmusy ṣafikun pe ẹnu ẹnikan loun ti kọkọ gbọ nipa kiko ẹyin to n di ọmọ ninu obinrin pamọ leyi to wa sun oun lati bẹrẹ sii ṣewadii siwaju si nipa rẹ ki oun to ṣe nile iwosan.

O ni nibayii, ọkan oun ti balẹ lati bẹrẹ sii wa ọkọ lai maa bẹru pe ọjọ n lọ lori oun gẹgẹ bi obinrin titi ti oun yoo fi pade ade ori ti yoo ba oun kalẹ.

Ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹrin ọdun yii ni Ashmusy jade lati wa sọrọ nipa bo ṣe fi awọn ẹyin idọmọ rẹ pamọ bi o tilẹ jẹ pe ọrọ yii fa awuyewuye lori ẹrọ ayelujara ti awọn kan n bẹnu atẹ lu fun nkan to ṣe nigba t’awọn kan n kii pe kaare ọmọ-ọdọ rere.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search