Ẹgbẹ awọn olukọ lorilẹede Naijira ẹka tipinlẹ Ọyọ ni wọn ti ṣe iwọde alalaafia lati fi aidunnu wọn han lori awọn olukọ ati akẹkọọ ti wọn jigbe l’awọn ile-ẹkọ nijọba ibilẹ Oriire.
Awọn ajinigbe ni wọn ṣe ikọlu si awọn ile-iwe ọhun ni ọjọ kẹẹdogun oṣu yii ti wọn si ko awọn olukọ ati akẹkọọ to le l’ogoji.
Awọn elekeru naa ni wọn ti n fi fọnran oriṣirisi to n bani lọkan jẹ sita to n ṣafihan bi wọn ṣe n fiya jẹ awọn ti wọn wa l’akolo wọn ninu igbo.
Lẹyin to fẹẹ to ọsẹ mẹta ti wọn ti wa ni igbekun l’awọn olukọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ ati sekọndiri ya bo titi lati pe fun igbesẹ kiakia lati doola wọn.
Awọn olufẹhonu han naa ti wọn bẹrẹ iwode lati agbegbe Iwo road nilu Ibadan ni wọn mu orin s’ẹnu lati pe fun idapada awọn ọmọ naa ati opin si igbesunmọmi.
Ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni wọn n ke’pe awọn ijọba lati ṣiṣẹ takuntakun ki opin le de ba eto aabo to mẹhe.