Alaga ẹgbẹ awọn gomina lorilẹde Naijiria to jẹ gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe apapọ awọn gomina n gbero lati ṣafikun owo oṣiṣẹ to kere julọ si ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira lati mu adinku ba ọrọ aje to le dọindọin.
AbdulRazaq sọ eyi lori itakun ibanidọrẹ Facebook rẹ nibi to ti ṣalaye pe erongba yii waye latari bi nkan ṣe gb’owo lori gege to n ṣokun fa ara to n ni awọn oṣiṣẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ awọn gomina n ba ijọba apapọ ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ jiroro lori ọna ati sanwo ti yoo rọ awọn oṣiṣẹ lọrun lai ni ipalara.
Alaga ẹgbẹ awọn gomina naa fikun pe ijiroro n lọ lọwọ lori bi owo oṣiṣẹ to kere ju naa ko ṣe ni fa apo awọn ijọba ipinlẹ ya.
O tẹsiwaju pe ijiroro naa da le ki ibadogba wa pẹlu agbara ati raja awọn oṣiṣẹ ati fifun ijọba laaye lati ṣe awọn iṣẹ amayedẹrun.
Ẹwẹ, ajafẹtọ ọmọ-niyan Omoyele Sowore ti bẹnu atẹ lu ọrọ ti awọn ẹgbẹ gomina sọ pe awọn n gbero lati ṣafikun owo oṣiṣẹ to kere julọ to si n sọ pe owo naa o to lati gbọ bukata awọn oṣiṣẹ.
Sowore sọ eyi ninu ọrọ kan to fi lede lori ẹrọ ayelujara nibi to ti n sọ pe owo naa o le to awọn oṣiṣẹ mọ lọwọ yii pẹlu bi nkan ṣe n f’ojoojumọ gb’owo lori.
O tẹsiwaju pe owo naa fẹẹ le ma to lati ra apo irẹsi kan ka to ṣẹṣẹ wa sọrọ lori owo ọkọ, ilera, ẹkọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ni oye awọn nkan ti awọn oṣiṣẹ n koju ye wọn ṣugbọn wọn ṣi n fun wọn lowo akuṣẹ t’awọn si n gbe igbe-aye fami-lete-ki-n-tu-tọ.
Owo oṣiṣẹ to kere ju bayi ni ẹgbẹrun lọna aadọrin leyi ti ọpọ awọn oṣiṣẹ n ke rora pe ko to lati gbọ bukata mọ latari nkan to n f’ojoojumọ gb’owo lori lorilẹede Naijira.