Gomina tẹlẹri nipinlẹ Kano, Rabiu Musa Kwankwanso ti bẹnu atẹ lu ọrọ to n lọ l’ode pe o n ṣiṣẹ labẹ lẹ fun Aarẹ Bola Tinubu fun idibo ọdun 2027.
Kwankwanso sọ eyi nibi ifọrọwerọ kan ti wọn ṣe fun. Nibẹ lo ti sọ pe awọn ti wọn n gbe iroyin naa ka o mo nipa oṣelu ni wọn ṣe le maa sọ bẹẹ.
O ni afi awọn ti laakaye wọn o ba to ni wọn maa sọ pe awọn n ba Tinubu ṣiṣẹ nitori oun ati awọn alatilẹyin oun wa pẹlu ẹgbẹ oṣelu NDC gbagbaagba fun ilọsiwaju orilẹede Naijiria.
Adije dupo Aarẹ tẹlẹri naa ṣalaye pe lootọ l’oun ati Tinubu ti jọ wa tipẹtipẹ ṣugbọn iyẹn o tumọ si pe awọn jọ ni eero kannaa nipa oṣelu. Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn mejeeji ti mọra lati ọdun to ti pẹ ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ l’awọn wa.
Kwankwanso wa fẹsun kan awọn tiwọn sunmọ aarẹ pe wọn o sọ ootọ nipa bi nkan ṣe ri lorilẹede Naijira fun. O ni kaka ki awọn oludamọran aarẹ f’ọkan si bi nkan ṣe maa daa ti ọrọ aje orilẹede Naijiria a si goke niṣe ni wọn n wa bi wọn ṣe maa wọ awọn gomina ati oloṣelu loriṣiriṣi wọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Agba oloṣelu naa sọrọ nipa ajọṣepọ rẹ pẹlu Peter Obi to si n ṣalaye pe lẹyin ipade lọpọlọpọ ati iṣiro ninu oṣelu l’oun fi ṣatilẹyin fun-un ati pe oun o lero pe ẹlomii le ṣe daadaa to ni ẹkun Guusu.
O tẹsiwaju pe asiko ṣi wa fun awọn lati kan si awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati ṣe awọn alaye lori gbogbo awọn ọrọ to n lọ nipa awọn bẹẹ lo n fi wọn lọkan balẹ pe afojusun ẹgbẹ oṣelu NDC ni lati fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni idari to yẹ.