Aburo Minisita fun ohun amuṣagbara tẹlẹri ati adije dupo gomina nipinlẹ Ọyọ Adebayo Adelabu, ni awọn agbebọn ti jigbe t’oun ti awọn ọmọ ibeji rẹ nilu Ibadan.
Ẹni kan ti ọrọ naa ṣ’oju rẹ ni oni ode yii ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ l’agbegbe Challenge ni ijọba ibilẹ guusu iwọ-oorun ipinlẹ Ọyọ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ l’orukọ gbogbo ẹbi Adebayo Adelabu, ọkan lara awọn agbẹnusọ rẹ, Femi Awogboro ni awọn ọdaran ajinigbe ji Arabirin Olaide Busayo Adegoke John-Paul ati awọn ibeji rẹ Peter ati Paul ni kutukutu aarọ yii.
Arabinrin Olaide to jẹ ọmọ ọdun mẹtalelogoji ni wọn fi tipatipa gbe ni nkan bii aago meje aabọ nigba to n gbe awọn ọmọ rẹ ti wọn jẹ ọmọ ọdun mejila lo ile-iwe.
Gẹgẹ bi ọrọ ti Femi sọ, Olaide ni abigbẹyin mama Olufunmilayo Aduke Adegoke Adelabu. Ko to di pe o fi iṣẹ silẹ l’ọdun to kọja, Olaide ṣiṣe pẹlu ile ifowopamọ ilẹ wa (CBN) ati ile-iṣẹ First Bank Pension Custodian.
Lẹyin to f’iṣẹ silẹ lo pada silu Ibadan pẹlu awọn ọmọ rẹ ni igbaradi lati lọ ba ọkọ rẹ, Ọgbẹni John Paul to ti fi orilẹede Naijiria silẹ lọ s’ilu Amẹrika.
Lẹsẹkẹsẹ ti iṣẹlẹ naa ṣẹ l’awọn ẹṣọ alaabo ti bẹrẹ si ni ṣe iwadii ti wọn si n gbe igbesẹ lati doola awọn mẹtẹẹta ati fi kele ofin gbe awọn ọdaran naa.