Ilumọọka onkọrin fuji Remi Aluko ti sọrọ lori aisan to n ba ja leyi to ti fa ko ma riran mọ. O sọ eyi lori ifọrọwanilẹnuwo kan ti fọnran ẹ n tan ka bayii.
Nigba to n sọrọ nipa ipo ti oju ẹ wa bayi, o ṣalaye pe oun ti n ba aarun oju ti wọn n pe ni Glaucoma ja lati ọdun pipẹ.
Remi Aluko ni oun ti ṣe iṣẹ abẹ oju tẹlẹ ṣugbọn lọwọ yii ko fẹẹ si iyatọ laarin oun ati afọju bayi. O ni n’iṣẹ l’oun n ṣamojuto ilera oun bayi.
O tẹsiwaju pe ọpọ awọn eeyan ni wọn o mọ pe oun ni aarun naa pẹlu bi oun o ṣe riran ṣugbọn oun o jẹ ki ailera naa fa ibanujẹ ọkan f’oun.
O dupẹ lọwọ Ọlọrun pe oun mọ itọju ara oun bi ẹni to riran. O ni oun ti pinnu lati ma ro ọrọ naa ju ki oun ma baa ni irẹwẹsi ọkan.
Remi Aluko ti ọpọ eeyan mọ si Igwe Fuji ati Stage Commander lo ja gbangba l’agbo fuji ni ẹni ọdun mẹẹdogun nilu Eko to si rin irin-ajo naa to fi di ilumọọka.