Awọn obi ati awọn ẹni ọrọ kan gbogbo lo ti n kọminu lori bi idanwo oniwe mẹwaa WASSCE ti ọdun 2026 ṣe n di oru fun awọn akẹẹkọ ni ipinlẹ Ọyọ ati awọn ibomiran l’orilẹ-ede Naijiria.
Awọn fọnran kan to jade l’ori ayelujara ni’bi ti awọn oluṣedanwo ti n ṣe idanwo ni alẹ lai si ina-ọba, to jẹ pe ina ara ẹrọ ibanisọrọ, atupa nkankan ni wọn fi n tan’na.
Ọpọlọpọ awọn eniyan paapaa julọ awọn obi lo ti f’ara ya l’ori iṣẹlẹ yii pe irufẹ amojuto wo gan-an lo wa fun awọn to n ṣe idanwo naa ati pe ewu nla ni ki idanwo o ma di aṣalẹ abi ilẹ-ṣu.
Koko ohun ti ọpọ to mẹnuba iṣẹlẹ naa n tọka si ni pe awọn eroja ati irinṣẹ eto idanwo naa ni ko de si ibudo Idanwo lasiko ti si n ṣ’okunfa ki idanwo o ma pẹ pupọ. Eleyii si ni ọpọ awọn obi ati alagbatọ n pe o nilo amojuto to yẹ.
Ẹwẹ, ajọ WAEC to n ṣ’eto idanwo oniwe-mẹwaa ni ko ti f’esi ṣugbọn ti oṣiṣẹ wọn kan ṣalaye labẹ aṣọ pe awọn akude kan ti ko ṣe e yẹ silẹ lo ba eto wọn ṣugbọn ti igbesẹ ti n lọ lati f’opin si iru iriri bẹẹ bẹrẹ lati ọjọ keji.
Ẹ ranti pe eto idanwo naa l’ọdun 2025 to kọja lọ naa ni akọsilẹ awọn akude kọọkan to ba eto wọn, l’eyi to tun di kun ifa’ra ya awọn ara-ilu l’asiko yii.