O ṣeeṣe ki gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde fi erongba rẹ lede lati dije dupo aarẹ lorilẹede yii nibi apejọ kan ti yoo waye ni gbọngan Mapo nilu Ibadan l’ọjọbọ ọsẹ yii.
Apejọ naa ti wọn pe ni “Unity Mega Rally Ibadan 2026” ni igbagbọ wa pe Seyi Makinde o fi kede erongba lati dije dupo aarẹ ati ikede ifọwọsowọpọ laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ati APM ni ipinlẹ Ọyọ.
Yatọ si pe yoo fi erongba tiẹ han, o tun ṣeeṣe ki Makinde fi oju awọn tiwọn n dije dupo oriṣiriṣi ni ipinlẹ ati ijọba apapọ han labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM.
Lara awọn ti wọn maa ṣe iṣaṣọloju fun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM ni kọmisọna tẹlẹri fun eto iṣuna nipinlẹ Ọyọ, Bimbo Adekanbi gẹgẹ bii adije dupo gomina, Stanley Olajide, Olufemi Ajadi ati Shina Peller gẹgẹ bii aṣoju nile igbimọ aṣofin agba. Awọn oludije nile igbimọ aṣojuṣofin agba ati ti ipinlẹ Oyo naa o ni gbẹyin nibi iṣaṣọloju naa.
Apejo yii ni yoo kọkọ bẹrẹ pẹlu ifọwọsiwe laarin igun ẹgbẹ oṣelu PDP ti Tanimu Turaki n lewaju fun ati awọn agba ẹgbẹ oṣelu APM gẹgẹ bii awọn kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe sọ.
Bi o tilẹ jẹ pe gomina o tii jade lati wa fi gbogbo ẹnu sọ pe oun ni lọkan lati dije, awọn ẹgbẹ alatilẹyin gbogbo tii n pe fun lati gbe apoti fun ipo aarẹ ni ọdun 2027 nitori wọn n’igbagbọ ninu iṣejọba rẹ.
Ti ẹ o ba gbagbe, ọpọ awọn ọmọ lẹyin gomina Seyi Makinde ni wọn ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APM ti ọpọ awọn eeyan si n sọ pe ko le ṣẹyin rẹ.